Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Kíróníkà 2:2-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. Sólómónì sì yan ẹgbẹ̀rún ní ọ̀nà àádọ́rin àwọn (70,000) ọkùnrin láti ru ẹrù àti ẹgbẹ̀rún ní ọ̀nà ọgọ́rin àwọn (80,000) ọkùnrin gẹ́gẹ́ bi olùgé-òkúta ní àwọn òkè àti ẹgbẹ̀rún mẹ́rìndínlógójì (36,000) gẹ́gẹ́ bí àwọn alábojútó lórí wọn.

3. Sólómónì rán iṣẹ́ yìí sí Hírámíà ọba Tírè:“Rán àwọn igi kédárì sí mi gẹ́gẹ́ bí o ti ṣe fún baba à mi Dáfídì. Nígbà tí ó fi igi kédárì ránsẹ́ sí i láti kọ́ ààfin tí ó ń gbé.

4. Nísinsin yìí, èmi n kọ́ ilé kan fún orúkọ Olúwa Ọlọ́run mi àti láti yà á sí mímọ́ fún un àti láti sun tùràrí olóòórùn dídùn níwájú rẹ̀, fún gbígbé àkàrà-ìfihàn ìgbàkúgbà, àti fún síse ẹbọ sísun ní gbogbo àárọ̀ àti ìrọ̀lẹ́ àti ní ọjọọjọ́ ìsinmi àti òṣùpá tuntun àti ní àpèjọ Olúwa Ọlọ́run wa. Èyí ni àsẹ fún Ísírẹ́lì láéláé.

5. “Ilé Olúwa tí èmi yóò kọ́ yóò tóbi, nítorí pé Ọlọ́run wa tóbi ju gbogbo àwọn Ọlọ́run mìíràn lọ.

6. Ṣùgbọ́n ta ni ó le è kọ́ ilé fún Olúwa, níwọ̀n ìgbà tí àwọn ọ̀run, àní ọ̀run tí ó ga jùlọ, kò ti le è gbà á? Ta ni èmi nígbà náà láti kọ́ ilé fún Olúwa, àyàfi ibi kan fún sísun ẹbọ níwájú rẹ̀?

7. “Nítorí náà, rán ọkùnrin kan sí mi, tí a kọ́ láti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú wúrà àti fàdákà àti idẹ àti irin, àti ní àwọ̀ àlùkò àti àwọ̀ pupa fòò àti ní awọ̀ oju ọ̀run, tí ó jẹ́ onímọ̀ nínú isẹ́ igi gbígbẹ́ láti ṣiṣẹ́ ní Júdà àti Jérúsálẹ́mù pẹ̀lú àwọn onímọ̀ oníṣọ̀nà tí Baba à mi Dáfídì pèsè.

8. “Fi igi òpépé ránṣẹ́ sí mi, pínì àti lígúmì àwọn igi láti Lébánónì, nítorí tí mo mọ̀ pé àwọn ọkùnrin rẹ ní ìmọ̀ nínú gígé igi rírẹ́. Àwọn ọkùnrin mi yóò ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn ọkùnrin rẹ.

9. Láti pèsè ọ̀pọ̀ igi rírẹ́ fún mi, nitorí ilé Olúwa tí mo kọ́ gbọdọ̀ tóbi kí o sì lógo púpọ̀.

10. Èmi yóò fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ, àwọn ọkùnrin onígi tí ó ń gé rírẹ́ náà ni ẹgbẹ̀rún kórísì (1,000), àlìkámà ilẹ̀ àti ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogún (20,000) kórísì ti bálì; ẹgbẹ́rùn lọ́nà (20,000) ogún ìwẹ̀ ọtí wáìnì àti ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogún ìwẹ̀ òróró Ólífì.”

Ka pipe ipin 2 Kíróníkà 2