Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Sámúẹ́lì 23:2-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. Dáfídì sì béèré lọ́dọ̀ Olúwa pé, “Ṣé kí èmi ó lọ kọlu àwọn ará Fílístínì wọ̀nyí bí?” Olúwa sì wí fún Dáfídì pé, “Lọ kí o sì kọlu àwọn ará Fílístínì kí o sì gba Kéílà sílẹ̀.”

3. Àwọn ọmọkùnrin tí ó wà lọ́dọ̀ Dáfídì sì wí fún un pé, “Wò ó, àwa ń bẹ̀rù níhín yìí ní Júdà; ǹjẹ́ yóò ti rí nígbà ti àwa bá dé Kéílà láti fi ojú ko ogun àwọn ara Fílístínì?”

4. Dáfídì sì tún béèrè lọ́dọ Olúwa. Olúwa sì dá a lóhùn, ó sì wí pé, “Dìde, kí o sọ̀kalẹ̀ lọ sí Kéílà, nítorí pé èmi ó fi àwọn ará Fílístínì náà lé ọ lọ́wọ́.”

5. Dáfídì àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ sì lọ sí Kéílà, wọ́n sì bá àwọn ará Fílístínì jà, wọ́n sì kó ohun ọ̀sìn wọn, wọ́n sì fi ìparun ńlá pa wọ́n. Dáfídì sì gba àwọn ará Kéílà sílẹ̀.

6. Ó sì ṣe, nígbà tí Ábíátarì ọmọ Áhímélékì fi sá tọ Dáfídì lọ ní Kéílà, ó sọ̀kalẹ̀ òun pẹ̀lú éfódù kan lọ́wọ́ rẹ̀.

7. A sì sọ fún Ṣọ́ọ̀lù pé Dáfídì wá sí Kéílà. Ṣọ́ọ̀lù sì wí pé, “Ọlọ́run ti fi í lé mi lọ́wọ́; nítorí tí ó ti sé ara rẹ̀ mọ́ ní ti wíwá tí ó wá sí ìlú tí ó ní ìlẹ̀kùn àti kẹrẹ.”

8. Ṣọ́ọ̀lù sì pe gbogbo àwọn ènìyàn náà jọ sí ogun, láti sọ̀kalẹ̀ lọ sí Kéílà, láti ká Dáfídì mọ́ àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀.

9. Dáfídì sì mọ̀ pé Ṣọ́ọ̀lù ti gbèrò búburú sí òun; ó sì wí fún Ábíátarì àlùfáà náà pé, “Mú éfódù náà wá níhínìnyìí!”

10. Dáfídì sì wí pé, “Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì, Lóòótọ́ ni ìránṣẹ́ rẹ ti gbọ́ pé Ṣọ́ọ̀lù ń wá ọ̀nà láti wá sí Kéílà, láti wá fọ́ ìlú náà nítorí mi.

Ka pipe ipin 1 Sámúẹ́lì 23