Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Sámúẹ́lì 20:27-38 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

27. Ṣùgbọ́n ní ọjọ́ kejì, ní ọjọ́ kejì oṣù, ààyè Dáfídì sì tún ṣófo. Nígbà náà ni Ṣọ́ọ̀lù wí fún ọmọ rẹ̀ Jónátanì pé, “Kí ni ó dé tí ọmọ Jésè kò fi wá síbi oúnjẹ, lánàá àti lónìí?”

28. Jónátanì sì dáhùn pé, “Dáfídì bẹ̀ mí tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ fún ààyè láti lọ sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù.

29. Ó wí pé, ‘Jẹ́ kí n lọ, nítorí pé ìdílé wa ń ṣe ìrúbọ ní ìlú, àwọn ẹ̀gbọ́n ọ̀n mi sì ti pàṣẹ fún mi láti wà níbẹ̀; tí èmi bá rí ojú rere ní ojú rẹ, jẹ́ kí n lọ láti lọ rí àwọn ẹ̀gbọ́n mi.’ Ìdí nì yí tí kò fi wá sí orí tábìlì oúnjẹ ọba.”

30. Ìbínú Ṣọ́ọ̀lù sì ru sí Jónátanì ó sì wí fún un pé, “Ìwọ ọmọ aláìgbọ́ràn àti ọlọ̀tẹ̀ búburú yìí, ṣé èmi kò ti mọ̀ pé, ìwọ ti yan ọmọ Jésè fún ìtìjú ti ara rẹ àti fún ìtìjú mọ̀mọ́ rẹ tí ó bí ọ?

31. Níwọ̀n ìgbà tí ọmọ Jésè bá wà láàyè lórí ilẹ̀ ayé, a kì yóò fi ẹṣẹ̀ ìwọ tàbí ti ìjọba rẹ múlẹ̀. Nísinsìn yìí ránṣẹ́ kí o sì lọ mú un wá fún mi, nítorí ó gbọ́dọ̀ kú!”

32. Jónátanì béèrè lọ́wọ́ baba rẹ̀ pé, “Èéṣe tí àwa yóò fi pa á? Kí ni ó ṣe?”

33. Ṣùgbọ́n Ṣọ́ọ̀lù ju ọ̀kọ̀ rẹ̀ sí Jónátánì láti gún un pa. Nígbà náà ni Jónátanì mọ̀ pé baba rẹ̀ mọ̀ ọ́n mọ̀ fẹ́ pa Dáfídì ni.

34. Bẹ́ẹ̀ ni Jónátanì sì fi ìbínú dìde kúrò ni ibi oúnjẹ, kò sì jẹun ni ọjọ́ kejì oṣù náà, inú rẹ̀ sì bàjẹ́ gidigidi fún Dáfídì, nítorí pé baba rẹ̀ dójú tì í.

35. Ó sì ṣe, ní òwúrọ̀ ni Jónátanì jáde lọ sí oko ní àkókò tí òun àti Dáfídì ti fí àdéhùn sí, ọmọdekùnrin kan sì wá pẹ̀lú rẹ̀.

36. Ó si wí fún ọmọdékùnrin rẹ̀ pé, “Sáré, kí o si wá àwọn ọfà tí èmi ó ta.” Bí ọmọdé náà sì ti ń sáré, òun sì tafà rékọjá rẹ̀.

37. Nígbà tí ọmọdékùnrin náà sì dé ibi ọfà tí Jónátanì ta, Jónátanì sì kọ sí ọmọdékùnrin náà ó sì wí pé, “Ọfà náà kò ha wà níwájú rẹ bi?”

38. Jónátanì sì kọ sí ọmọdékùnrin náà pé, “Sáré! Yára! Má ṣe dúró!” Ọmọdékùnrin Jónátanì sì ṣa àwọn ọfà náà, ó sì tọ olúwa rẹ̀ wá.

Ka pipe ipin 1 Sámúẹ́lì 20