Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Sámúẹ́lì 10:1-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Sámúẹ́lì sì mú ìgò kékeré tí òróró wà nínú rẹ̀, ó sì dà á sí orí Ṣọ́ọ̀lù. Ó sì fi ẹnu kò ó ní ẹnu, wí pé, “Olúwa kò ha tí fi òróró yàn ọ ní olóri í lórí ohun ìní rẹ̀?

2. Bí ìwọ bá kúrò lọ́dọ̀ mi lónìí, ìwọ yóò bá ọkùnrin méjì pàdé lẹ́bàá ibojì Rákélì ní Sélísà, ní agbégbé Bẹ́ńjámínì. Wọ́n yóò sọ fún ọ pé, ‘Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí ìwọ jáde lọ láti wá ní wọn tí rí. Nísinsìn yìí, baba à rẹ tí dákẹ́ kò ronú nípa wọn mọ́, ó sì ń damú nípa à rẹ. Ó ń béèrè, “Kí ni èmi yóò ṣe nípà ọmọ mi?” ’

3. “Nígbà náà, ìwọ yóò lọ láti ibẹ̀ títí yóò fi dé ibi igi Tábórì ńlá. Ọkùnrin mẹ́ta tí wọ́n ń gòkè lọ sọ́dọ̀ Ọlọ́run ní Bẹ́tẹ́lì yóò pàdé rẹ níbẹ̀. Ọ̀kan yóò mú ọmọ ewúrẹ́ mẹ́ta lọ́wọ́, èkejì, iṣù àkàrà mẹ́ta àti ẹ̀kẹtà yóò mú ìgò wáìnì.

4. Wọ́n yóò kí ọ, wọn yóò sì fún ọ ní ìṣù àkàrà méjì, tí ìwọ yóò gbà lọ́wọ́ ọ wọn.

5. “Lẹ́yìn náà, ìwọ yóò lọ sí òkè Ọlọ́run, níbi tí ẹgbẹ́ ogun àwọn Fílístínì wà. Bí ìwọ ti ń súnmọ́ ìlú náà, ìwọ yóò bá àwọn wòlíì tí ó tò lọ́wọ̀ọ̀wọ́ bọ̀ láti ibi gíga, pẹ̀lú líárì, támborí àti fèrè àti gìta níwájú wọn, wọn yóò sì máa sọ àṣọtẹ́lẹ̀.

6. Ẹ̀mí Olúwa yóò sì bà lé ọ, nínú agbára, ìwọ yóò sì di ẹni ọ̀tọ̀.

7. Bí ìwọ bá ti rí àmì wọ̀nyí, ṣe ohunkóhun tí ọwọ́ rẹ bá bà láti ṣe, nítorí Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ.

8. “Lọ ṣáájú mi sí Gílgálì. Èmi yóò sọ̀kalẹ̀ tọ̀ ọ́ wá láti rú ẹbọ sísun àti láti rú ẹbọ ìrẹ́pọ̀, ṣùgbọ́n ìwọ gbọdọ̀ dúró fún ọjọ́ méje títí èmi yóò fi wá sí ọ̀dọ̀ rẹ láti sọ fún ọ ohun tí ó yẹ tí ìwọ yóò ṣe.”

9. Bí Ṣọ́ọ̀lù ti yípadà láti fi Sámúẹ́lì sílẹ̀, Ọlọ́run yí ọkàn Ṣọ́ọ̀lù padà àti pé gbogbo àmì wọ̀nyí sì wá sí ìmúṣẹ ní ọjọ́ náà.

10. Nígbà tí wọ́n dé òkè náà, àwọn wòlíì tí ó ń tò ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́ pàdé rẹ̀, Ẹ̀mí Ọlọ́run bà lé e nínú agbára, ó sì darapọ̀ bá wọ́n sọ àṣọtẹ́lẹ̀.

11. Nígbà tí gbogbo àwọn tí ó ti mọ̀ ọ́n tẹ́lẹ̀ rí i tó ń sọ àṣọtẹ́lẹ̀ pẹ̀lú àwọn wòlíì, wọ́n bi ara wọn, “Kí ni ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀ sí ọmọ Kíṣì yìí. Ṣé Ṣọ́ọ̀lù wà lára àwọn wòlíì ní?”

12. Ọkùnrin kan tí ó ń gbé níbẹ̀ dáhùn pé, “Ta ni baba wọn?” Ó ti di ohun tí a fi ń dáṣà pé, ǹjẹ́ Ṣọ́ọ̀lù náà wà lára àwọn wòlíì bí?

13. Lẹ́yìn tí Ṣọ́ọ̀lù dákẹ́ sísọ àṣọtẹ́lẹ̀, ó lọ sí ibi gíga.

Ka pipe ipin 1 Sámúẹ́lì 10