Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Ọba 7:12-24 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

12. Àgbàlá ńlá náà yíkákiri ògiri pẹ̀lú ọ̀wọ́ mẹ́ta òkúta gbígbẹ́ àti ọ̀wọ́n kan igi ìdábùú ti kédárì, bí ti inú lọ́hùn ún àgbàlá ilé Olúwa pẹ̀lú ìloro rẹ̀.

13. Sólómónì ọba ránṣẹ́ sí Tírè, ó sì mú Hírámù wá,

14. ẹni tí ìyá rẹ̀ jẹ́ opó láti inú ẹ̀yà Náfítalì àti tí baba rẹ̀ sì ṣe ará Tírè, alágbẹ̀dẹ idẹ. Hírámù sì kún fún ọgbọ́n àti òye, àti ìmọ̀ láti ṣe oríṣiríṣi iṣẹ́ idẹ. Ó wá sọ́dọ̀ Sólómónì ọba, ó sì ṣe gbogbo iṣẹ́ tí wọ́n gbé fún un.

15. Ó sì dá ọ̀wọ̀n idẹ méjì, ọ̀kọ̀ọ̀kan sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ méjìdínlógún ní gíga okùn ìgbọ̀nwọ́ méjìlá ni ó sì yí wọn ká.

16. Ó sì tún ṣe ìparí méjì ti idẹ dídá láti fi sókè àwọn ọ̀wọ̀n náà, ìparí kan sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn ún ní gíga.

17. Onírúurú iṣẹ́, àti ohun híhun ẹ̀wọ̀n fún àwọn ìparí tí ń bẹ lórí àwọn ọ̀wọ̀n náà, méje fún ìparí kọ̀ọ̀kan.

18. Ó sì ṣe àwọn Pómégíránátè ní ọ̀wọ́ méjì yíkákiri lára iṣẹ́ ọ̀wọ̀n náà, láti fi bo àwọn ìparí ti ń bẹ lókè, ó sì ṣe bẹ́ẹ̀ fún ìparí kejì.

19. Àwọn ìparí tí ń bẹ ní òkè àwọn ọ̀wọ̀n náà tí ń bẹ ní ọ̀dẹ̀dẹ̀ náà dàbí àwòrán lílì, ìgbọ̀nwọ́ mẹ́rin ní gíga.

20. Lórí àwọ̀n ìparí ọ̀wọ́n méjì náà lókè, wọ́n sì súnmọ́ ibi tí ó yẹ lára ọ̀wọ̀n tí ó wà níbi iṣẹ́ àwọ̀n, wọ́n sì jẹ́ igba (200) pómégíránátè ní ọ̀wọ́ yíkákiri.

21. Ó sì gbé àwọn ọ̀wọn náà ró ní ìloro tẹ́ḿpìlì, ó sì pe orúkọ ọ̀wọ̀n tí ó wà ní gúṣù ní Járánì àti èyí tí ó wà ní àríwá ní Bóásì.

22. Àwọn ìparí lókè sì jẹ́ àwòrán lílì. Bẹ́ẹ̀ ni iṣẹ́ ti àwọn ọ̀wọ̀n sì parí.

23. Ó sì ṣe agbádá dídá, ó ṣe bíríkítí, ó wọn ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá láti etí kan dé èkejì àti ìgbọ̀nwọ́ márùn ún ní gíga rẹ̀. Ó sì gba okùn ọgbọ̀n ìgbọ̀nwọ́ láti wọ̀n yíí ká.

24. Ní ìṣàlẹ̀ etí rẹ̀, kókó wà yíi ká, mẹ́wàá nínú ìgbọ̀nwọ́ kan. Ó yí agbádá náà káàkiri, a dá kókó náà ní ọ̀wọ́ méjì, nígbà tí a dá a.

Ka pipe ipin 1 Ọba 7