Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Ọba 7:1-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Sólómónì sì lo ọdún mẹ́talá láti fi kọ́ ààfin rẹ̀, ó sì parí gbogbo iṣẹ́ ààfin rẹ̀.

2. Ó kọ́ ilé igbó Lébánónì pẹ̀lú; gígùn rẹ̀ sì jẹ́ ọgọ́rùn ún ìgbọ̀nwọ́, àti àádọ́ta ìgbọ̀nwọ́ ní ìbú rẹ̀ àti gíga rẹ̀ ọgbọ̀n ìgbọ̀nwọ́; pẹ̀lú ọwọ́ mẹ́rin igi kédárì, àti ìdábú igi kédárì lórí òpó náà.

3. A sì fi igi kédárì tẹ́ ẹ lókè lórí yàrá tí ó jókòó lórí ọ̀wọ̀n márùnlélógójì, mẹ́ẹ̀dógún ní ọ̀wọ́.

4. Fèrèsé rẹ̀ ni a gbé sókè ní ọ̀wọ́ mẹ́ta, kọjú sí ara wọn.

5. Gbogbo ilẹ̀kùn àti òpó sì dọ́gba ní igun mẹ́rin: wọ́n sì wà ní apá iwájú ní ọ̀wọ́ mẹ́ta, wọ́n kọjú sí ara wọn.

6. Ó sì fi ọ̀wọ̀n ṣe gbàngàn ìdájọ́: àádọ́ta ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn rẹ̀, ìbú rẹ̀ sì jẹ́ ọgbọ̀n (30) ìgbọ̀nwọ́. Ìloro kan sì wà níwájú rẹ̀ pẹ̀lú ọ̀wọ̀n àti ìbòrí ìgúnwà níwájú wọn.

7. Ó sì ṣe gbàngàn ìtẹ́, gbàngàn ìdájọ́, níbi tí yóò ti ṣe ìdájọ́, ó sì fi igi kédárì bò ó láti ilẹ̀ dé àjà ilé.

8. Ààfin rẹ̀ níbi tí yóò sì gbé wà ní àgbàlá lẹ́yìn ààfin, irú kan náà ni wọ́n. Sólómónì sì kọ́ ààfin tí ó rí bí gbàngàn yìí fún ọmọbìnrin Fáráò tí ó ní ní aya.

9. Gbogbo wọ̀nyí láti òde dé apá àgbàlá ńlá, àti láti ìpìlẹ̀ dé ìbòrí òkè ilé, wọ́n sì jẹ́ òkúta iyebíye gẹ́gẹ́ bí ìwọ̀n òkúta gbígbẹ, tí a fi ayùn rẹ́ nínú àti lóde.

10. Ìpìlẹ̀ náà jẹ́ òkúta iyebíye, àní òkúta ńlá ńlá, àwọn mìíràn wọn ìgbọ̀nwọ́ mẹ̀wàá, àwọn mìíràn ìgbọ̀nwọ́ mẹ́jọ.

11. Lókè ni òkúta iyebíye wà nípa ìwọ̀n òkúta tí a gbé àti igi kédárì.

12. Àgbàlá ńlá náà yíkákiri ògiri pẹ̀lú ọ̀wọ́ mẹ́ta òkúta gbígbẹ́ àti ọ̀wọ́n kan igi ìdábùú ti kédárì, bí ti inú lọ́hùn ún àgbàlá ilé Olúwa pẹ̀lú ìloro rẹ̀.

13. Sólómónì ọba ránṣẹ́ sí Tírè, ó sì mú Hírámù wá,

Ka pipe ipin 1 Ọba 7