Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Ọba 21:1-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ó sì ṣe lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí Nábótì ará Jésérẹ́lì sì ní ọgbà àjàrà kan ní Jésérẹ́lì, ní ẹ̀gbẹ́ ààfin Áhábù ọba Samáríà.

2. Áhábù sì wí fún Nábótì pé, “Fún mi ní ọgbà àjàrà rẹ, kí èmi kí ó fi ṣe ọgbà-ewébẹ̀, nítorí tí ó súnmọ́ tòsí ilé mi; Èmi yóò sì fún ọ ní ọgbà àjàrà tí ó sàn jù ú lọ dípò rẹ̀; tàbí bí ó bá sì dára ní ojú rẹ, èmi yóò fi iye owó rẹ̀ fún ọ.”

3. Ṣùgbọ́n Nábótì wí fún Áhábù pé, “Olúwa má jẹ́ kí èmi fi ogún àwọn bàbá mi fún ọ.”

4. Áhábù sì wá sí ilé rẹ̀, ó wugbọ́, inú rẹ̀ sì bàjẹ́ nítorí ọ̀rọ̀ tí Nábótì ará Jésérẹ́lì sọ fún un; nítorí tí ó wí pé, “Èmi kì yóò fún ọ ní ogún àwọn bàbá mi.” Ó sì dùbúlẹ̀ lórí ibùsùn rẹ̀, ó sì yí ojú rẹ̀ padà, kò sì fẹ́ jẹun.

5. Jésébélì aya rẹ̀ sì tọ̀ ọ́ wá, ó sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Èéṣe tí inú rẹ fi bàjẹ́, Èéṣe tí ìwọ kò sì jẹun?”

6. Ó sì dá a lóhùn pé, “Nítorí tí mo wí fún Nábótì ará Jésérẹ́lì pé, ‘Ta ọgbà àjàrà rẹ fún mi, tàbí bí ó bá wù ọ́, Èmi yóò fún ọ ní ọgbà àjàrà mìíràn ní ipò rẹ̀.’ Ṣùgbọ́n ó wí pé, ‘Èmi kì yóò fún ọ ní ọgbà àjàrà mi.’ ”

7. Jésébélì aya rẹ̀ sì wí pé, “Ṣé báyìí ni ìwọ yóò ṣe ṣe bí ọba lórí Ísírẹ́lì? Dìde, jẹun! Kí o sì jẹ́ kí inú rẹ̀ dùn. Èmi yóò sì fún ọ ní ọgbà àjàrà Nábótì ará Jésérẹ́lì.”

8. Bẹ́ẹ̀ ni ó kọ̀wé ní orúkọ Áhábù, ó sì fi èdìdì rẹ̀ dì í, ó sì fi ìwé náà ránṣẹ́ sí àwọn àgbààgbà àti àwọn ọlọ́lá tí ó ń gbé ní ìlú Nábótì pẹ̀lú rẹ̀.

9. Nínú àwọn ìwé náà, ó kọ pé:“Ẹ kéde ààwẹ̀, kí ẹ sì fi Nábótì sí ipò ọlá láàrin àwọn ènìyàn.

10. Ṣùgbọ́n kí ẹ fi ènìyàn méjì, ẹni búburú ṣíwájú rẹ̀ láti jẹ́rìí pa á wí pé, ó bú Ọlọ́run àti ọba. Nígbà náà ni kí ẹ mú u jáde, kí ẹ sì sọ ọ́ ní òkúta pa.”

11. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn àgbààgbà àti àwọn ọlọ́lá tí wọ́n ń ṣe ará ìlú Nábótì sì ṣe gẹ́gẹ́ bí Jésébélì ti ránṣẹ́ sí wọn.

12. Wọ́n sì kéde ààwẹ̀, wọ́n sì fi Nábótì sí ipò ọlá láàrin àwọn ènìyàn.

13. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọkùnrin méjì sì dé, àwọn ẹni búburú, wọ́n sì jókòó ṣíwájú rẹ̀, wọ́n sì jẹ́rìí pa Nábótì níwájú àwọn ènìyàn wí pé, “Nábótì ti bú Ọlọ́run àti ọba.” Nígbà náà ni wọ́n mú jáde kúrò ní ìlú, wọ́n sì sọ ọ́ ní òkúta pa.

14. Nígbà náà ni wọ́n ránṣẹ́ sí Jésébélì wí pé: “A ti sọ Nábótì ní òkúta, ó sì kú.”

Ka pipe ipin 1 Ọba 21