Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Ọba 2:29-44 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

29. A sì sọ fún Sólómónì ọba pé Jóábù ti sá lọ sínú àgọ́ Olúwa àti pé ó wà ní ẹ̀gbẹ́ pẹpẹ. Nígbà náà ni Sólómónì pàṣẹ fún Bénáyà ọmọ Johóíadà pé, “Lọ, kí o sì kọlù ú.”

30. Bénáyà sì wọ inú àgọ́ Olúwa, ó sì wí fún Jóábù pé, “Ọba sọ wí pé, Jáde wá.”Ṣùgbọ́n ó dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́, Èmi yóò kú níhìn ín.”Bénáyà sì mú èsì fún ọba, “Báyìí ni Jóábù ṣe dá mi lóhùn.”

31. Ọba sì pàṣẹ fún Bénáyà pé, “Ṣe bí ó ti wí. Kọ lù ú, kí o sì sin ín, kí o sì mú ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ kúrò lọ́dọ̀ mi àti kúrò lọ́dọ̀ ilé bàbá mi, tí Jóábù ti ta sílẹ̀.

32. Olúwa yóò sì san ẹ̀jẹ̀ tí ó ti ta sílẹ̀ padà fún un, nítorí tí ó kọlu ọkùnrin méjì, ó sì fi idà rẹ̀ pa wọ́n, Dáfídì bàbá mi kò sì mọ̀ àwọn méjèèjì ni. Ábínérì ọmọ Nérì olórí ogun Ísírẹ́lì, àti Ámásà ọmọ Jétérì olórí ogun Júdà, wọ́n jẹ́ olódodo, wọ́n sì sàn ju òun fúnrarẹ̀ lọ.

33. Kí ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ wọn wá sórí Jóábù àti sórí irú-ọmọ rẹ̀ títí láé. Ṣùgbọ́n sórí Dáfídì àti irú-ọmọ rẹ̀, sí ilé rẹ̀ àti sí ìtẹ́ rẹ̀, ni kí àlàáfíà Olúwa wà títí láé.”

34. Bẹ́ẹ̀ ni Bénáyà ọmọ Jéhóíádà sì gòkè lọ, ó sì kọlu Jóábù, ó sì pa á, a sì sin ín ní ilẹ̀ ibojì ara rẹ̀ ní ihà.

35. Ọba sì fi Bénáyà ọmọ Jéhóíádà jẹ olórí ogun ní ipò Jóábù àti Sádókù àlùfáà ní ipò Ábíátarì.

36. Nígbà náà ni ọba ránṣẹ́ sí Ṣíméhì ó sì wí fún un pé, “Kọ́ ilé fún ara rẹ ní Jérúsálẹ́mù, kí o sì máa gbé ibẹ̀, ṣùgbọ́n kí o má sì ṣe lọ sí ibòmíràn.

37. Ọjọ́ tí ìwọ bá jáde, tí o sì kọjá pẹ̀tẹ́lẹ̀ Kídírónì, kí ìwọ kí ó mọ̀ dájúdájú pé ìwọ yóò kú; ẹ̀jẹ̀ rẹ yóò sì wà lórí ara rẹ.”

38. Ṣíméhì sì dá ọba lóhùn pé, “Ohun tí ìwọ sọ dára. Ìránṣẹ́ rẹ yóò ṣe bí Olúwa mi ọba ti wí.” Ṣíméhì sì gbé ní Jérúsálẹ́mù fún ìgbà pípẹ́.

39. Ṣùgbọ́n lẹ́yìn ọdún mẹ́ta, àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ Síméì méjì sì sá lọ sọ́dọ̀ Ákíṣì ọmọ Máákà, ọba Gátì, a sì sọ fún Síméì pé, “Àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ méjì wà ní Gátì.”

40. Fún ìdí èyí, ó sì di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ ní gàárì, ó sì lọ sọ́dọ̀ Ákíṣì ní Gátì láti wá àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni Síméì sì lọ, ó sì mú àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ padà bọ̀ láti Gátì.

41. Nígbà tí a sì sọ fún Sólómónì pé Síméì ti lọ láti Jérúsálẹ́mù sí Gátì, ó sì ti padà,

42. Ọba pe Síméì lẹ́jọ́, ó wí fún un pé, “Ǹjẹ́ èmi kò ti mú ọ búra ní ti Olúwa, èmi sì ti kìlọ̀ fún ọ pé, ‘Ní ọjọ́ tí ìwọ bá kúrò láti lọ sí ibikíbi, kí o mọ̀ dájú pé ìwọ yóò kú’? Nígbà náà ni ìwọ sì sọ fún mi pé, ‘Ohun tí ìwọ sọ dára. Èmi yóò ṣe ìgbọ́ràn.’

43. Èéṣe nígbà náà tí ìwọ kò pa ìbúra Olúwa mọ́, àti kí o sì ṣe ìgbọ́ràn sí àṣẹ tí mo pa fún ọ?”

44. Ọba sì tún wí fún Síméì pé, “Ìwọ mọ̀ ní ọkàn rẹ gbogbo búburú tí ìwọ ti ṣe sí Dáfídì baba mi. Báyìí, Olúwa yóò san gbogbo ìṣe búburú rẹ padà fún ọ.

Ka pipe ipin 1 Ọba 2