Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Ọba 1:8-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

8. Ṣùgbọ́n Ṣádókù àlùfáà, Bẹ́náyà ọmọ Jóhóíádà, Nátanì wòlíì, Ṣímè àti ọ̀rẹ́ rẹ̀ Rélì àti olórí ogun Dáfídì ni kò darapọ̀ mọ́ Àdóníjà

9. Nígbà náà ni Àdóníjà fi àgùntàn àti màlúù àti ẹran ọ̀sìn tí ó sanra rúbọ níbi òkúta Sóhélétì tí ń bẹ lẹ́gbẹ̀ẹ́ Énrógélì. Ó sì pe gbogbo àwọn arákùnrin rẹ̀, àwọn ọmọ ọba, àti gbogbo àwọn ọkùnrin Júdà tí wọ́n jẹ́ ìránṣẹ́ ọba.

10. Ṣùgbọ́n kò pe Nátanì Wòlíì tàbí Bénáyà tàbí àwọn olórí tàbí Sólómónì arákùnrin rẹ̀.

11. Nígbà náà ni Nátanì bèrè lọ́wọ́ Bátíṣébà, ìyá Sólómọ́nì pé, “Ǹjẹ́ ìwọ kò gbọ́ pé Àdóníjà, ọmọ Hágítì ti jọba láìjẹ́ pé Dáfídì Olúwa wa mọ̀ síi?

12. Ǹjẹ́ nísinsin yìí, jẹ́ kí èmi gbà ọ́ ní ìmọ̀ràn bí ìwọ ṣe lè gba ẹ̀mí rẹ là àti ẹ̀mí ọmọ rẹ Sólómónì.

13. Lọ sọ́dọ̀ Dáfídì ọba, kí o sì wí fún un pé, ‘Olúwa mi ọba, ǹjẹ́ ìwọ kò búra fún ìránṣẹ́ rẹ pé, “Dájúdájú Sólómónì ọmọ rẹ ni yóò Jọba lẹ́yìn mi, yóò sì jókòó lórí ìtẹ́ mi?” Èéṣe nígbà náà tí Àdóníjà fi jọba?’

14. Níwọ̀n ìgbà tí ìwọ sì wà níbẹ̀, tí o sì ń bá ọba sọ̀rọ̀ èmi yóò wá, láti wádìí ohun tí o ti sọ.”

15. Bẹ́ẹ̀ ni Bátíṣébà lọ rí ọba ní inú yàrá rẹ̀, ọba sì gbó gidigidi níbi tí Ábíságì ará Súnémù sì ń ṣe ìránṣẹ́ fún ọba.

16. Bátíṣébà sì tẹríba, ó sì kúnlẹ̀ níwájú ọba.Ọba sì béèrè pé, “Kí ni ìwọ ń fẹ́?”

17. Ó sì wí fún ọba pé, “Olúwa mi; ìwọ fúnra rẹ fi Olúwa Ọlọ́run rẹ búra fún ìránṣẹ́ rẹ pé: ‘Sólómónì ọmọ rẹ yóò jọba lẹ́yìn mi, yóò sì jókòó lórí ìtẹ́ mi.’

18. Ṣùgbọ́n nísinsin yìí Àdóníjà ti di ọba, ìwọ, ọba Olúwa mi, kò sì mọ̀ nípa rẹ̀.

19. Òun sì ti fi ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ màlúù, àti ẹran tí ó ní ọ̀rá, àti àgùntàn rúbọ, ó sì pe gbogbo àwọn ọmọ ọba, àti Ábíátarì àlùfáà àti Jóábù balógun, ṣùgbọ́n kò sì pe Sólómónì ìránṣẹ́ rẹ.

20. Olúwa mi ọba, ojú gbogbo Ísírẹ́lì ń bẹ lára rẹ, láti mọ ẹni tí yóò jókòó lórí ìtẹ́ Olúwa mi ọba lẹ́yìn rẹ.

Ka pipe ipin 1 Ọba 1