Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Ọba 1:39-52 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

39. Sádókù àlùfáà sì mú ìwo òróró láti inú àgọ́, ó sì dà á sí Sólómónì lórí. Nígbà náà ni wọ́n sì fọn fèrè, gbogbo àwọn ènìyàn sì ké pé, “Kí Sólómónì ọba kí ó pẹ́!”

40. Gbogbo ènìyàn sì gòkè tọ̀ ọ́ lẹ́yìn wọ́n ń fọn ìpè, wọ́n sì ń yọ ayọ̀ ńlá, tó bẹ́ẹ̀ tí ilẹ̀ mì fún ìró wọn.

41. Àdóníjà àti gbogbo awọn àlejò tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ gbọ́ ọ́ bí wọ́n ti ń jẹun tán, wọ́n ń gbọ́ ipè, Jóábù sì wí pé, “Kí ní ìtumọ̀ gbogbo ariwo nínú ìlú yìí?”

42. Bí ó sì ti ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, Jónátanì ọmọ Ábíátarì àlùfáà sì dé, Àdóníjà sì wí pé, “Wọlé wá, ọkùnrin yíyẹ ìwọ gbọ́dọ̀ mú ìròyìn rere wá.”

43. Jónátanì sì dá a lóhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́ rárá, Olúwa wa Dáfídì ọba ti fi Sólómónì jọba.

44. Ọba sì ti rán Sádókù àlùfáà, Nátanì wòlíì, Bénáyà ọmọ Jéhóíádà àti àwọn ará Kérétì àti Pélétì pẹ̀lú rẹ̀, wọ́n sì ti gbé e gun ìbaka ọba,

45. Sádókù àlùfáà àti Nátanì wòlíì ti fi òróró yàn án ní ọba ní Gíhónì. Lati ibẹ̀ ni wọ́n ti gòkè wá pẹ̀lú ayọ̀, ìlú sì ń hó pẹ̀lú rẹ̀. Èyí ni ariwo tí ẹ̀yin ń gbọ́.

46. Sólómónì sì ti jókòó lórí ìtẹ́ ìjọba rẹ̀.

47. Àwọn ìránṣẹ́ ọba sì ti tún wá láti bá Olúwa wa Dáfídì Ọba yọ̀, wí pé, ‘Kí Ọlọ́run rẹ̀ mú orúkọ Sólómónì lókìkí ju tirẹ̀ lọ àti kí ìtẹ́ rẹ̀ kí ó pọ̀ ju tirẹ̀ lọ!’ Ọba sì tẹ ara rẹ̀ ba lórí ibùsùn rẹ̀,

48. ó sì wí pé, ‘Ògo ni fún Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì, ẹni tí ó ti jẹ́ kí ojú mi rí ẹnìkan tí ó jókòó lórí ìtẹ́ mi lónìí.’ ”

49. Nígbà náà ni gbogbo àwọn àlejò tí ó wà lọ́dọ̀ Àdóníjà dìde ní ìdágìrì, wọ́n sì túká.

50. Ṣùgbọ́n Àdóníjà sì bẹ̀rù Sólómónì, ó lọ, ó sì di ìwo pẹpẹ mú.

51. Nígbà náà ni a sì sọ fún Sólómónì pé, “Adóníjà bẹ̀rù Sólómónì Ọba, ó sì di ìwo pẹpẹ mú, Ó wí pé, ‘Jẹ́ kí ọba Sólómónì búra fún mi lónìí pé, òun kì yóò fi idà pa ìránṣẹ́ rẹ̀.’ ”

52. Sólómónì sì dáhùn pé, “Bí ó bá fi ara rẹ̀ hàn láti jẹ́ ẹni ọ̀wọ̀, irun orí rẹ̀ kan kì yóò sì bọ́ sílẹ̀; ṣùgbọ́n bí a bá rí búburú kan ní ọwọ́ rẹ̀ òun yóò kú.”

Ka pipe ipin 1 Ọba 1