Sádókù àlùfáà àti Nátanì wòlíì ti fi òróró yàn án ní ọba ní Gíhónì. Lati ibẹ̀ ni wọ́n ti gòkè wá pẹ̀lú ayọ̀, ìlú sì ń hó pẹ̀lú rẹ̀. Èyí ni ariwo tí ẹ̀yin ń gbọ́.