Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Ọba 1:16-28 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

16. Bátíṣébà sì tẹríba, ó sì kúnlẹ̀ níwájú ọba.Ọba sì béèrè pé, “Kí ni ìwọ ń fẹ́?”

17. Ó sì wí fún ọba pé, “Olúwa mi; ìwọ fúnra rẹ fi Olúwa Ọlọ́run rẹ búra fún ìránṣẹ́ rẹ pé: ‘Sólómónì ọmọ rẹ yóò jọba lẹ́yìn mi, yóò sì jókòó lórí ìtẹ́ mi.’

18. Ṣùgbọ́n nísinsin yìí Àdóníjà ti di ọba, ìwọ, ọba Olúwa mi, kò sì mọ̀ nípa rẹ̀.

19. Òun sì ti fi ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ màlúù, àti ẹran tí ó ní ọ̀rá, àti àgùntàn rúbọ, ó sì pe gbogbo àwọn ọmọ ọba, àti Ábíátarì àlùfáà àti Jóábù balógun, ṣùgbọ́n kò sì pe Sólómónì ìránṣẹ́ rẹ.

20. Olúwa mi ọba, ojú gbogbo Ísírẹ́lì ń bẹ lára rẹ, láti mọ ẹni tí yóò jókòó lórí ìtẹ́ Olúwa mi ọba lẹ́yìn rẹ.

21. Bí kò ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà tí Olúwa mi ọba bá sùn pẹ̀lú àwọn bàbá rẹ̀, wọn yóò sì ka èmi àti Sólómónì sí ẹlẹ́ṣẹ̀.”

22. Bí ó sì ti ń bá ọba sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, Nátanì wòlíì sì wọlé.

23. Wọ́n sì sọ fún ọba pé, “Nátanì wòlíì wà níbí.” Ó sì lọ ṣíwájú ọba, ó wólẹ̀, ó sì dojúbolẹ̀.

24. Nátanì sì wí pé, “Ǹjẹ́ ìwọ, Olúwa mi ọba, ti sọ pé Àdóníjà ni yóò jẹ ọba lẹ́yìn rẹ àti pé òun ni yóò jókòó lórí ìtẹ́ rẹ?

25. Ó sì ti sọ̀kalẹ̀ lọ ní òní, ó sì ti rúbọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ màlúù, àti ẹran ọlọ́ràá àti àgùntàn. Ó sì ti pe gbogbo àwọn ọmọ ọba, Balógun àti Ábíátarì àlùfáà. Ní sinsin yìí wọ́n ń jẹ wọ́n ń mu pẹ̀lú rẹ̀, wọ́n sì wí pé, ‘Kí Àdóníjà ọba kí ó pẹ́!’

26. Ṣùgbọ́n èmi ìránṣẹ́ rẹ, àti ṣádókù àlùfáà, àti Bẹ́náyà ọmọ Jéhóiádà, àti Sólómónì ìránṣẹ́ rẹ ni kò pè.

27. Ṣé nǹkan yìí ni Olúwa mi ọba ti ṣe láìjẹ́ kí àwọn ìránṣẹ́ rẹ mọ ẹni tí yóò jókòó lórí ìtẹ́ Olúwa mi ọba lẹ́yìn rẹ?”

28. Nígbà náà ni Dáfídì ọba wí pé, “Pe Bátíṣébà wọlé wá.” Ó sì wá ṣíwájú ọba, ó sì dúró níwájú rẹ̀.

Ka pipe ipin 1 Ọba 1