Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Kíróníkà 27:1-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Wọ̀nyí ni ìwé àkójọ orúkọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, àwọn olórí àwọn ìdílé, àwọn balógun ẹgbẹgbẹ̀rún àti àwọn balógun ọrọrún àti àwọn ìjòyè wọn. Tí ó n sin ọba nínú gbogbo ohun tí ó kan ìpín àwọn ọmọ ogun tí ó wà lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn ní oṣoṣù ní gbogbo ọdún. Ìpín kọ̀ọ̀kan jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́rin ólé ẹgbàá mẹ́rin (24,000) ọkùnrin.

2. Ní ti alákòóso lórí ìpín kìn-ín-ni fún oṣù kìn-ín-ní jẹ́ Jáṣóbéámù ọmọ Ṣábídiélì àwọn ọkùnrin ẹgbẹ̀rún mẹ́rin ólé ẹgbàá mẹ́rin ní ó wà ní abẹ́ (24,000) ìpín tirẹ̀.

3. Ó jẹ́ ìran ọmọ pérésì àti olóyè fún gbogbo àwọn ìjòyè ológun fún oṣù kìn-ín-ní.

4. Alákòóso fún ìpín àwọn ọmọ-ogun fún oṣù kejì jẹ́ Dódáì ará Áhóhì; Míkílótì jẹ́ olórí ìpín tirẹ̀. Ọkùnrin ẹgbàá ni ó wà ní ìpín tirẹ̀. (24,000).

5. Olórí àwọn ọmọ ogun ẹlẹ́ẹ̀kẹta fún oṣù kẹta jẹ́ Bénáyà ọmọ Jéhóíádà àlùfáà. Ó jẹ́ olóyè, àwọn ọkùnrin ẹgbàá méjìlá ní ó wà ní ìpín tirẹ̀. (24,000).

6. Èyí ni Bénáyà náà tí ó jẹ́ ọkùnrin ńlá láàrin àwọn ọgbọ̀n àti lórí àwọn ọgbọ̀n. Ọmọ Rẹ̀ Ámíṣábádì jẹ́ alákóso lórí ìpín tirẹ̀.

7. Ẹlẹ́ẹ̀kẹrin fún oṣù kẹrin, jẹ́ Ásáhélì arákùnrin Jóábù: ọmọ Rẹ̀ Ṣébádáyà jẹ́ arọ́pò Rẹ̀. Ẹgbàá méjìlá ọkùnrin (24,000) ni ó wà ní ìpín Rẹ̀.

8. Ẹ̀káàrún fún oṣù kárùn-ún, jẹ́ olórí Ṣámíhútì ará Íṣíráhì. Ẹgbàá méjìlá ọkùnrin (24,000) ní ó wà ní ìpín tirẹ̀.

Ka pipe ipin 1 Kíróníkà 27