1. Wọ̀nyí ni ìwé àkójọ orúkọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, àwọn olórí àwọn ìdílé, àwọn balógun ẹgbẹgbẹ̀rún àti àwọn balógun ọrọrún àti àwọn ìjòyè wọn. Tí ó n sin ọba nínú gbogbo ohun tí ó kan ìpín àwọn ọmọ ogun tí ó wà lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn ní oṣoṣù ní gbogbo ọdún. Ìpín kọ̀ọ̀kan jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́rin ólé ẹgbàá mẹ́rin (24,000) ọkùnrin.
2. Ní ti alákòóso lórí ìpín kìn-ín-ni fún oṣù kìn-ín-ní jẹ́ Jáṣóbéámù ọmọ Ṣábídiélì àwọn ọkùnrin ẹgbẹ̀rún mẹ́rin ólé ẹgbàá mẹ́rin ní ó wà ní abẹ́ (24,000) ìpín tirẹ̀.
3. Ó jẹ́ ìran ọmọ pérésì àti olóyè fún gbogbo àwọn ìjòyè ológun fún oṣù kìn-ín-ní.
4. Alákòóso fún ìpín àwọn ọmọ-ogun fún oṣù kejì jẹ́ Dódáì ará Áhóhì; Míkílótì jẹ́ olórí ìpín tirẹ̀. Ọkùnrin ẹgbàá ni ó wà ní ìpín tirẹ̀. (24,000).
5. Olórí àwọn ọmọ ogun ẹlẹ́ẹ̀kẹta fún oṣù kẹta jẹ́ Bénáyà ọmọ Jéhóíádà àlùfáà. Ó jẹ́ olóyè, àwọn ọkùnrin ẹgbàá méjìlá ní ó wà ní ìpín tirẹ̀. (24,000).
6. Èyí ni Bénáyà náà tí ó jẹ́ ọkùnrin ńlá láàrin àwọn ọgbọ̀n àti lórí àwọn ọgbọ̀n. Ọmọ Rẹ̀ Ámíṣábádì jẹ́ alákóso lórí ìpín tirẹ̀.
7. Ẹlẹ́ẹ̀kẹrin fún oṣù kẹrin, jẹ́ Ásáhélì arákùnrin Jóábù: ọmọ Rẹ̀ Ṣébádáyà jẹ́ arọ́pò Rẹ̀. Ẹgbàá méjìlá ọkùnrin (24,000) ni ó wà ní ìpín Rẹ̀.
8. Ẹ̀káàrún fún oṣù kárùn-ún, jẹ́ olórí Ṣámíhútì ará Íṣíráhì. Ẹgbàá méjìlá ọkùnrin (24,000) ní ó wà ní ìpín tirẹ̀.
9. Ẹ̀kẹfà fún oṣù kẹfà jẹ́ Írà ọmọ Íkéṣì, ará Tékóì. Ọkùnrin ẹgbàá méjìlá (24,000) ni ó wà ní ìpín Rẹ̀.
10. Ẹ̀kéje fún oṣù kéje jẹ́ Hélésì ará Pélónì, ará Éfíráímù. Ọkùnrin ẹgbàá méjìlá (24,000) ni o wà ní ìpín Rẹ̀.
11. Ẹ̀kẹjọ fún oṣù kẹjọ jẹ́ Ṣíbékáì ará Húṣátì, ará Ṣéráhì ọkùnrin ẹgbàá méjìlá (24,000) ni ó wà ní ìpín Rẹ̀.
12. Ẹ̀kẹsàn-án fún oṣù kẹ́sàn-án jẹ́. Ábíésérì ará Ánátótì, ará Bénjámínì ọkùnrin ẹgbàá méjìlá (24,000) ni ó wà ní ìpín Rẹ̀.
13. Ẹ̀kẹwàá fún oṣù kẹ́wàá jẹ́ Máháráì ará Nétófátì, ará Ṣéráhì ọkùnrin ẹgbàá méjìlá (24,000) ni ó wà ní ìpín Rẹ̀.
14. Ìkọkànlá fún oṣù kọkànlá jẹ́ Bénáyà ará pírátónì ará Éfíráímù ọkùnrin ẹgbàá méjìlá (24,000) ni ó wà ní ìpín tirẹ̀.
15. Ìkejìlá fún oṣù kejìlá jẹ́ Hélídáì ará Nétófátì láti ìdílé Ótíníélì. Ẹgbàá méjìlá ọkùnrin (24,000) ni ó wà ní ìpín tirẹ̀.
16. Àwọn ìjòyè lórí àwọn ẹ̀yà tí Ísírẹ́lì:lórí àwọn ará Réúbẹ́nì: Éliésérì ọmọ Ṣíkírì;lórí àwọn ará Ṣíméónì: Ṣéfátíyà ọmọ Mákà;
17. lórí Léfì: Háṣábíà ọmọ Kémúélì;lori Árónì: Ṣádókù;
18. lórí Júdà: Élíhù arákùnrin Dáfídì;lóri Ísákárì: Ómírì ọmọ Míkáélì;