39. Ọ̀kan ninu àwọn arúfin tí wọ́n kàn mọ́ agbelebu pẹlu rẹ̀ ń sọ ìsọkúsọ pé, “Ṣebí ìwọ ni Mesaya! Gba ara rẹ là kí o sì gba àwa náà là!”
40. Ṣugbọn ekeji bá a wí, ó ní, “Ìwọ yìí, o kò bẹ̀rù Ọlọrun. Ìdájọ́ kan náà ni wọ́n dá fún un bíi tiwa.
41. Ní tiwa, ó tọ́ bẹ́ẹ̀, nítorí èrè iṣẹ́ wa ni à ń jẹ. Ṣugbọn òun ní tirẹ̀ kò ṣẹ̀ rárá.”
42. Ó bá sọ fún Jesu pé, “Ranti mi nígbà tí o bá dé inú ìjọba rẹ.”
43. Jesu bá sọ fún un pé, “Mo wí fún ọ, lónìí yìí ni ìwọ yóo wà pẹlu mi ní ọ̀run rere.”
44-45. Nígbà tí ó tó bí agogo mejila ọ̀sán, òkùnkùn bo gbogbo ilẹ̀ títí di agogo mẹta ọ̀sán. Oòrùn kò ràn. Aṣọ ìkélé Tẹmpili ya sí meji.
46. Jesu kígbe, ó ní, “Baba, ní ọwọ́ rẹ ni mo fi ẹ̀mí mi lé.” Nígbà tí ó ti sọ báyìí tán, ó mí kanlẹ̀, ó bá kú.
47. Nígbà tí ọ̀gágun náà rí ohun tí ó ṣẹlẹ̀, ó yin Ọlọrun lógo, ó ní, “Lóòótọ́, olódodo ni ọkunrin yìí.”
48. Nígbà tí gbogbo àwọn eniyan tí wọ́n péjọ, tí wọn wá wòran, rí ohun tí ó ṣẹlẹ̀, ńṣe ni wọ́n pada lọ, tí wọ́n káwọ́ lérí pẹlu ìbànújẹ́.
49. Gbogbo àwọn ojúlùmọ̀ rẹ̀ ati àwọn obinrin tí wọ́n tẹ̀lé e wá láti Galili, gbogbo wọn dúró lókèèrè, wọ́n ń wo gbogbo ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀.
50-51. Ọkunrin kan wà ninu àwọn ìgbìmọ̀ tí ó ń jẹ́ Josẹfu. Ó jẹ́ eniyan rere ati olódodo. Òun kò bá wọn lóhùn sí ète tí wọ́n pa, ati ohun tí wọ́n ṣe sí Jesu. Ó jẹ́ ará Arimatia, ìlú kan ní Judia. Ó ń retí ìjọba Ọlọrun.
52. Òun ni ó lọ sọ́dọ̀ Pilatu, tí ó bèèrè òkú Jesu.
53. Ó sọ òkú náà kalẹ̀ lórí agbelebu, ó fi aṣọ funfun wé e, ó bá tẹ́ ẹ sinu ibojì tí wọ́n gbẹ́ sinu àpáta, tí wọn kò ì tíì tẹ́ òkú sí rí.
54. Ọjọ́ náà jẹ̀ Ọjọ́ Ìpalẹ̀mọ́, Ọjọ́ Ìsinmi fẹ́rẹ̀ bẹ̀rẹ̀.