1. Nínú ìwé mi ìṣáájú, Tèófilọ́sì, ni mo ti kọ ní ti ohun gbogbo tí Jésù bẹ̀rẹ̀ sí ṣe àti kọ́
2. Títí ó fi di ọjọ́ tí a gbà á lọ sókè ọ̀run, lẹ́yìn tí ó ti sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́ fún àwọn àpósítélì tí ó yàn
3. Lẹ́yìn ìjìyà rẹ̀, ó fi ara rẹ̀ hàn fún wọn àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀rí tí ó dájú pé òun wà láàyè. Ó fi ara hàn wọ́n fún ogójì ọjọ́, ó sì sọ̀rọ̀ nípa ìjọba Ọlọ́run.
4. Nígbà kan, bí ó sì ti ń jẹun pẹ̀lú wọn, ó pàṣẹ yìí fún wọn: “Ẹ má ṣe kúrò ní Jerúsálémù, ṣùgbọ́n ẹ dúró de ẹ̀bùn tí Baba mi se ìlérí, èyí tí ẹ̀yin tí gbọ́ lẹ́nu mi.
5. Nítorí Jòhánù fi omi bamitíìsì yín, ṣùgbọ́n ní ọjọ́ díẹ̀ sí i, a o fi Ẹ̀mí Mímọ́ bamitíìsì yín.”
6. Nítorí náà, nígbà tí wọ́n sì péjọ pọ̀, wọn bi í léèrè pé, “Olúwa, láti ìgbà yí lọ ìwọ yóò ha mú ìjọba padà fún Ísírẹ́lì bí?”
7. Ó sì wí fún wọn pé, “Kì í ṣe ti yín ni láti mọ àkókò tàbí ìgbà tí Baba ti yàn nípa àṣẹ òun tìkárarẹ̀.
8. Ṣùgbọ́n ẹ̀yin yóò gba agbára, nígbà tí Ẹ̀mí Mímọ́ bá bà lé e yín: ẹ̀yin yóò sì máa ṣe ẹlẹ́rìí mi ni Jerúsálémù, àti ní gbogbo Jùdíà, àti ní Samaríà, àti títí dé òpin ilẹ̀ ayé.”
9. Nígbà tí ó sì tí wí nǹkan wọ̀nyí, a gbà á sókè lójú wọn; ìkùùkuu àwọsánmọ̀ sì gbà á kúrò lójú wọn.
10. Bí wọ́n sì ti tẹjúmọ́ ojú ọ̀run bí ó ti ń lọ sókè, lójijì, àwọn ọkùnrin méjì tí ó wọ aṣọ funfun dúró létí ọ̀dọ̀ wọn.
11. Wọ́n sì wí pé, “Ẹ̀yin ara Gálílì, è é ṣe tí ẹ̀yin fi dúró tí ẹ̀ ń wo ojú ọ̀run? Jésù yìí, tí a gbà sókè ọ̀run kúrò lọ́wọ́ yín, yóò padà bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹ ti rí tí ó ń lọ sì ọ̀run.”
12. Lẹ́yìn náà ni wọ́n padà sí Jerúsálému láti orí òkè ti a ń pè ni Ólífì, tí ó tó ìwọ̀n ìrìn ọjọ́ ìsinmi kan.
13. Nígbà tí wọn sì wọlé, wọn lọ sí ìyàrá òkè, níbi tí wọ́n ń gbé. Àwọn tó wà níbẹ̀ ni Pétérù, àti Jákọ́bù àti Jòhánù, àti Áńdérù, àti Fílípì, àti Tọ́másì, Bátóléméù, àti Mátíù, Jákọ́bù ọmọ Álíféù, àti Símónì Sélótì, àti Júdà arakùnrin Jákọ́bù.