Ìṣe Àwọn Àpósítélì 1:13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)
Nígbà tí wọn sì wọlé, wọn lọ sí ìyàrá òkè, níbi tí wọ́n ń gbé. Àwọn tó wà níbẹ̀ ni Pétérù, àti Jákọ́bù àti Jòhánù, àti Áńdérù, àti Fílípì, àti Tọ́másì, Bátóléméù, àti Mátíù, Jákọ́bù ọmọ Álíféù, àti Símónì Sélótì, àti Júdà arakùnrin Jákọ́bù.