Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mak 11:16-31 Yorùbá Bibeli (YCE)

16. Kò si jẹ ki ẹnikẹni ki o gbe ohun èlo kọja larin tẹmpili.

17. O si nkọ́ni, o nwi fun wọn pe, A ko ti kọwe rẹ̀ pe, Ile adura fun gbogbo orilẹ-ède li a o ma pè ile mi? ṣugbọn ẹnyin ti ṣọ di ihò awọn ọlọsà.

18. Awọn akọwe ati awọn olori alufa si gbọ́, nwọn si nwá ọ̀na bi nwọn o ti ṣe pa a run: nitori nwọn bẹ̀ru rẹ̀, nitori ẹnu yà gbogbo ijọ enia si ẹkọ́ rẹ̀.

19. Nigbati alẹ ba si lẹ, a jade kuro ni ilu.

20. Bi nwọn si ti nkọja lọ li owurọ, nwọn ri igi ọpọtọ na gbẹ ti gbongbo ti gbongbo.

21. Peteru si wa iranti o wi fun u pe, Rabbi, wò bi igi ọpọtọ ti iwọ fi bú ti gbẹ.

22. Jesu si dahùn o si wi fun wọn pe, Ẹ ni igbagbọ́ si Ọlọrun.

23. Lõtọ ni mo wi fun nyin, Ẹnikẹni ti o ba wi fun òke yi pe, Ṣidi, ki o si bọ sinu okun; ti kò ba si ṣiyemeji li ọkàn rẹ̀, ṣugbọn ti o ba gbagbọ́ pe ohun ti on wi yio ṣẹ, yio ri bẹ̃ fun u.

24. Nitorina mo wi fun nyin, Ohunkohun ti ẹnyin ba tọrọ nigbati ẹ ba ngbadura, ẹ gbagbọ́ pe ẹ ti ri wọn gbà na, yio si ri bẹ̃ fun nyin.

25. Nigbati ẹnyin ba si duro ngbadura, ẹ darijì, bi ẹnyin ba ni ohunkohun si ẹnikẹni: ki Baba nyin ti mbẹ li ọrun ba le dari ẹṣẹ nyin jì nyin pẹlu.

26. Ṣugbọn bi ẹnyin ko ba dariji, Baba nyin ti mbẹ li ọrun kì yio si dari ẹ̀ṣẹ nyin jì nyin.

27. Nwọn si tún wá si Jerusalemu: bi o si ti nrìn kiri ni tẹmpili, awọn olori alufa, ati awọn akọwe, ati awọn agbàgba, tọ̀ ọ wá,

28. Nwọn si wi fun u pe, Aṣẹ wo li o fi nṣe nkan wọnyi? tali o si fun ọ li aṣẹ yi lati mã ṣe nkan wọnyi?

29. Jesu si dahùn o si wi fun wọn pe, Emi ó bi nyin lẽre ọ̀rọ kan, ki ẹ si da mi lohùn, emi o si sọ fun nyin aṣẹ ti emi fi nṣe nkan wọnyi.

30. Baptismu Johanu lati ọrun wá ni, tabi lati ọdọ enia? ẹ da mi lohùn.

31. Nwọn si ba ara wọn gbèro, wipe, Bi awa ba wipe, Lati ọrun wá ni: on o wipe, Ẽha ti ṣe ti ẹnyin ko fi gbà a gbọ́?

Ka pipe ipin Mak 11