Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Joh 19:3-19 Yorùbá Bibeli (YCE)

3. Nwọn si wipe, Kabiyesi, Ọba awọn Ju! nwọn si fi ọwọ́ wọn gbá a loju.

4. Pilatu si tún jade, o si wi fun wọn pe, Wo o, mo mu u jade tọ̀ nyin wá, ki ẹnyin ki o le mọ̀ pe, emi kò ri ẹ̀ṣẹ kan lọwọ rẹ̀.

5. Nitorina Jesu jade wá, ti on ti ade ẹgún ati aṣọ elesè àluko. Pilatu si wi fun wọn pe, Ẹ wò ọkunrin na!

6. Nitorina nigbati awọn olori alufa, ati awọn onṣẹ ri i, nwọn kigbe wipe, Kàn a mọ agbelebu, kàn a mọ agbelebu. Pilatu wi fun wọn pe, Ẹ mu u fun ara nyin, ki ẹ si kàn a mọ agbelebu: nitoriti emi ko ri ẹ̀ṣẹ lọwọ rẹ̀.

7. Awọn Ju da a lohùn wipe, Awa li ofin kan, ati gẹgẹ bi ofin wa o yẹ lati kú, nitoriti o fi ara rẹ̀ ṣe Ọmọ Ọlọrun.

8. Nitorina nigbati Pilatu gbọ́ ọ̀rọ yi ẹ̀ru tubọ ba a.

9. O si tun wọ̀ inu gbọ̀ngan idajọ lọ, o si wi fun Jesu pe, Nibo ni iwọ ti wá? Ṣugbọn Jesu kò da a lohùn.

10. Nitorina Pilatu wi fun u pe, Emi ni iwọ ko fọhun si? iwọ kò mọ̀ pe, emi li agbara lati dá ọ silẹ, emi si li agbara lati kàn ọ mọ agbelebu?

11. Jesu da a lohun pe, Iwọ kì ba ti li agbara kan lori mi, bikoṣepe a fi i fun ọ lati oke wá: nitorina ẹniti o fi mi le ọ lọwọ li o ni ẹ̀ṣẹ pọ̀ju.

12. Nitori eyi Pilatu nwá ọ̀na lati dá a silẹ: ṣugbọn awọn Ju kigbe, wipe, Bi iwọ ba dá ọkunrin yi silẹ, iwọ kì iṣe ọrẹ́ Kesari: ẹnikẹni ti o ba ṣe ara rẹ̀ li ọba, o sọ̀rọ òdi si Kesari.

13. Nitorina nigbati Pilatu gbọ́ ọ̀rọ wọnyi, o mu Jesu jade wá, o si joko lori itẹ́ idajọ ti a npè ni Okuta-titẹ, ṣugbọn li ede Heberu, Gabbata.

14. O jẹ Ipalẹmọ́ ajọ irekọja, o jẹ iwọn wakati ẹkẹfa: o si wi fun awọn Ju pe, Ẹ wò Ọba nyin!

15. Nitorina nwọn kigbe wipe, Mu u kuro, mu u kuro, kàn a mọ agbelebu. Pilatu wi fun wọn pe, Emi o ha kàn Ọba nyin mọ agbelebu bi? Awọn olori alufa dahùn wipe,

16. Awa kò li ọba bikoṣe Kesari. Nigbana li o fà a le wọn lọwọ lati kàn a mọ agbelebu.Wọ́n bá gba Jesu lọ́wọ́ Pilatu.

17. Nitorina nwọn mu Jesu, o si jade lọ, o rù agbelebu fun ara rẹ̀ si ibi ti a npè ni Ibi-agbari, li ede Heberu ti a npè ni Golgota:

18. Nibiti nwọn gbé kàn a mọ agbelebu, ati awọn meji miran pẹlu rẹ̀, niha ikini ati nìha keji, Jesu si wà larin.

19. Pilatu si kọ iwe akọle kan pẹlu, o si fi i le ori agbelebu na. Ohun ti a si kọ ni, JESU TI NASARETI ỌBA AWỌN JU.

Ka pipe ipin Joh 19