Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Iṣe Apo 21:21-29 Yorùbá Bibeli (YCE)

21. Nwọn si ti ròhin rẹ fun wọn pe, Iwọ nkọ́ gbogbo awọn Ju ti o wà lãrin awọn Keferi pe, ki nwọn ki o kọ̀ Mose silẹ, o si nwi fun wọn pe ki nwọn ki o máṣe kọ awọn ọmọ wọn ni ilà mọ́, ati ki nwọn ki o máṣe rìn gẹgẹ bi àṣa wọn.

22. Njẹ ewo ni ṣiṣe? ijọ kò le ṣaima pejọ pọ̀: dajudaju nwọn ó gbọ́ pe, iwọ de.

23. Njẹ eyi ti awa ó wi fun ọ yi ni ki o ṣe: Awa li ọkunrin mẹrin ti nwọn ni ẹ̀jẹ́ lara wọn;

24. Awọn ni ki iwọ ki o mu, ki o si ṣe iwẹnumọ pẹlu wọn ki o si ṣe inawo wọn, ki nwọn ki o le fá ori wọn: gbogbo enia yio si mọ̀ pe, kò si otitọ kan ninu ohun ti nwọn gbọ si ọ; ṣugbọn pe, iwọ tikararẹ nrìn dede pẹlu, iwọ si npa ofin mọ́.

25. Ṣugbọn niti awọn Keferi ti o gbagbọ́, awa ti kọwe, a si ti pinnu rẹ̀ pe, ki nwọn pa ara wọn mọ kuro ninu ohun ti a fi rubọ si oriṣa, ati ẹ̀jẹ ati ohun ilọlọrùnpa, ati àgbere.

26. Nigbana ni Paulu mu awọn ọkunrin na; ni ijọ keji o ṣe iwẹnumọ pẹlu wọn, o si wọ̀ inu tẹmpili lọ, o sọ ìgba ti ọjọ ìwẹ̀numọ́ na yio pé titi a fi rubọ fun olukuluku wọn.

27. Nigbati ọjọ meje si fẹrẹ pé, ti awọn Ju ti o ti Asia wa ri i ni tẹmpili, nwọn rú gbogbo awọn enia soke, nwọn nawọ́ mu u.

28. Nwọn nkigbe wipe, Ẹnyin enia Israeli, ẹ gbà wa: Eyi li ọkunrin na, ti nkọ́ gbogbo enia nibigbogbo lòdi si awọn enia, ati si ofin, ati si ibi yi: ati pẹlu o si mu awọn ara Hellene wá si tẹmpili, o si ti ba ibi mimọ́ yi jẹ.

29. Nitori nwọn ti ri Trofimu ará Efesu pẹlu rẹ̀ ni ilu, ẹniti nwọn ṣebi Paulu mu wá sinu tẹmpili.

Ka pipe ipin Iṣe Apo 21