Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Iṣe Apo 19:2-12 Yorùbá Bibeli (YCE)

2. O wi fun wọn pe, Ẹnyin ha gbà Ẹmí Mimọ́ na nigbati ẹnyin gbagbọ́? Nwọn si wi fun u pe, Awa kò gbọ́ rara bi Ẹmí Mimọ́ kan wà.

3. O si wipe, Njẹ baptismu wo li a ha baptisi nyin si? Nwọn si wipe, Si baptismu ti Johanu.

4. Paulu si wipe, Nitõtọ, ni Johanu fi baptismu ti ironupiwada baptisi, o nwi fun awọn enia pe, ki nwọn ki o gbà ẹniti mbọ̀ lẹhin on gbọ, eyini ni Kristi Jesu.

5. Nigbati nwọn si gbọ́, a baptisi wọn li orukọ Jesu Oluwa.

6. Nigbati Paulu si gbe ọwọ́ le wọn, Ẹmí Mimọ́ si bà le wọn; nwọn si nfọ̀ ède miran, nwọn si nsọ asọtẹlẹ.

7. Iye awọn ọkunrin na gbogbo to mejila.

8. Nigbati o si wọ̀ inu sinagogu lọ, o fi igboiya sọ̀rọ li oṣù mẹta, o nfi ọ̀rọ̀ we ọ̀rọ̀, o si nyi wọn lọkan pada si nkan ti iṣe ti ijọba Ọlọrun.

9. Ṣugbọn nigbati ọkàn awọn miran ninu wọn di lile, ti nwọn kò si gbagbọ́, ti nwọn nsọ̀rọ ibi si Ọna na niwaju ijọ enia, o lọ kuro lọdọ wọn, o si yà awọn ọmọ-ẹhin sọtọ̀, o si nsọ asọye li ojojumọ́ ni ile-iwe Tirannu.

10. Eyi nlọ bẹ̃ fun iwọn ọdún meji; tobẹ̃ ti gbogbo awọn ti ngbe Asia gbọ́ ọ̀rọ Jesu Oluwa, ati awọn Ju ati awọn Hellene.

11. Ọlọrun si ti ọwọ́ Paulu ṣe iṣẹ aṣẹ akanṣe,

12. Tobẹ̃ ti a fi nmu gèle ati ibantẹ́ ara rẹ̀ tọ̀ awọn olokunrun lọ, arùn si fi wọn silẹ, ati awọn ẹmi buburu si jade kuro lara wọn.

Ka pipe ipin Iṣe Apo 19