Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Pet 2:12-25 Yorùbá Bibeli (YCE)

12. Ki ìwa nyin larin awọn Keferi kí o dara; pe, bi nwọn ti nsọ̀rọ nyin bi oluṣe buburu, nipa iṣẹ rere nyin, ti nwọn o mã kiyesi, ki nwọn ki o le mã yìn Ọlọrun logo li ọjọ ìbẹwo.

13. Ẹ mã tẹriba fun gbogbo ìlana enia nitori ti Oluwa: ibãṣe fun ọba, bi fun olori;

14. Tabi fun awọn bãlẹ, bi fun awọn ti a rán lati ọdọ rẹ̀ fun igbẹsan lara awọn ti nṣe buburu, ati fun iyìn awọn ti nṣe rere.

15. Bẹ̃ sá ni ifẹ Ọlọrun, pe ni rere iṣe, ki ẹ le dá òpe awọn wère enia lẹkun:

16. Bi omnira, laisi lo omnira nyin fun ohun bibo arakàn nyin mọlẹ, ṣugbọn bi ẹrú Ọlọrun.

17. Ẹ bọ̀wọ fun gbogbo enia. Ẹ fẹ awọn ará. Ẹ bẹru Ọlọrun. Ẹ bọ̀wọ fun ọba.

18. Ẹnyin ọmọ-ọ̀dọ, ẹ mã tẹriba fun awọn oluwa nyin pẹlu ìbẹru gbogbo; ki iṣe fun awọn ẹni rere ati oniwa tutu nikan, ṣugbọn fun awọn onrorò pẹlu.

19. Nitoripe eyi ni ìtẹwọgba, bi enia ba fi ori tì ibanujẹ, ti o si njìya laitọ́, nitori ọkàn rere si Ọlọrun.

20. Nitori ogo kili o jẹ, nigbati ẹ ba ṣẹ̀ ti a si lù nyin, bi ẹ ba fi sũru gbà a? ṣugbọn nigbati ẹnyin ba nṣe rere; ti ẹ si njiya, bi ẹnyin ba fi sũru gbà a, eyi ni itẹwọgbà lọdọ Ọlọrun.

21. Nitori inu eyi li a pè nyin si: nitori Kristi pẹlu jìya fun nyin, o fi apẹrẹ silẹ fun nyin, ki ẹnyin ki o le mã tọ̀ ipasẹ rẹ̀:

22. Ẹniti kò dẹṣẹ̀, bẹni a kò si ri arekereke lì ẹnu rẹ̀:

23. Ẹni, nigbati a kẹgan rẹ̀, ti kò si pada kẹgan; nigbati o jìya, ti kò si kilọ; ṣugbọn o fi ọ̀ran rẹ̀ le ẹniti nṣe idajọ ododo lọwọ:

24. Ẹniti on tikararẹ̀ fi ara rẹ̀ rù ẹ̀ṣẹ wa lori igi, pe ki awa ki o le di okú si ẹ̀ṣẹ ki a si di ãye si ododo: nipa ìnà ẹniti a mu nyin larada.

25. Nitori ẹnyin ti nṣako lọ bi agutan, ṣugbọn nisisiyi ẹnyin pada si ọdọ Oluṣọ-agutan ati Biṣopu ọkàn nyin.

Ka pipe ipin 1. Pet 2