Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Kor 7:17-35 Yorùbá Bibeli (YCE)

17. Ṣugbọn gẹgẹ bi Ọlọrun ti pín fun olukuluku enia, bi Oluwa ti pè olukuluku, bẹ̃ni ki o si mã rìn. Bẹ̃ni mo si nṣe ìlana ninu gbogbo ijọ.

18. A ha pè ẹnikan ti o ti kọla? ki o má si ṣe di alaikọla. A ha pè ẹnikan ti kò kọla? ki o máṣe kọla.

19. Ikọla ko jẹ nkan, ati aikọla kò jẹ nkan, bikoṣe pipa ofin Ọlọrun mọ́.

20. Ki olukuluku enia duro ninu ìpe nipasẹ eyi ti a ti pè e.

21. A ha pè ọ, nigbati iwọ jẹ ẹrú? máṣe kà a si: ṣugbọn bi iwọ ba le di omnira, kuku ṣe eyini.

22. Nitori ẹniti a pè ninu Oluwa, ti iṣe ẹrú, o di ẹni omnira ti Oluwa: gẹgẹ bẹ̃ li ẹniti a pè ti o jẹ omnira, o di ẹrú Kristi.

23. A ti rà nyin ni iye kan; ẹ máṣe di ẹrú enia.

24. Ará, ki olukuluku enia, ninu eyi ti a pè e, ki o duro ninu ọkanna pẹlu Ọlọrun.

25. Ṣugbọn nipa ti awọn wundia, emi kò ni aṣẹ Oluwa: ṣugbọn mo fun nyin ni imọran bi ẹniti o ri ãnu Oluwa gbà lati jẹ olododo.

26. Nitorina mo rò pe eyi dara nitori wahalà isisiyi, eyini ni pe, o dara fun enia ki o wà bẹ̃.

27. A ti dè ọ mọ́ aya ri bi? máṣe wá ọ̀na lati tú kuro. A ti tú ọ kuro lọwọ aya bi? máṣe wá aya ni.

28. Ṣugbọn bi iwọ ba si gbeyawo, iwọ kò dẹṣẹ: bi a ba si gbé wundia ni iyawo, on kò dẹṣẹ. Ṣugbọn irú awọn wọnni yio ni wahalà nipa ti ara: ṣugbọn mo dá nyin si.

29. Ṣugbọn eyi ni mo wi, ará, pe kukuru li akokò: lati isisiyi lọ pe ki awọn ti o li aya ki o dabi ẹnipe nwọn kò ni rí;

30. Ati awọn ti nsọkun, bi ẹ́nipe nwọn kò sọkun rí; ati awọn ti nyọ̀, bi ẹnipe nwọn kò yọ̀ rí; ati awọn ti nrà, bi ẹnipe nwọn kò ni rí;

31. Ati awọn ti nlò ohun aiye yi bi ẹniti kò ṣaṣeju: nitori aṣa aiye yi nkọja lọ.

32. Ṣugbọn emi nfẹ ki ẹnyin ki o wà laiṣe aniyàn. Ẹniti kò gbeyawo ama tọju ohun ti iṣe ti Oluwa, bi yio ti ṣe le wù Oluwa:

33. Ṣugbọn ẹniti o gbeyawo ama ṣe itọju ohun ti iṣe ti aiye, bi yio ti ṣe le wù aya rẹ̀.

34. Iyatọ si wà pẹlu larin obinrin ti a gbe ni iyawo ati wundia. Obinrin ti a kò gbe ni iyawo a mã tọju ohun ti iṣe ti Oluwa, ki on ki o le jẹ mimọ́ li ara ati li ẹmí: ṣugbọn ẹniti a gbé ni iyawo a ma tọju ohun ti iṣe ti aiye, bi yio ti ṣe le wù ọkọ rẹ̀.

35. Eyi ni mo si nwi fun ère ara nyin; kì iṣe lati dẹkun fun nyin, ṣugbọn nitori eyi ti o tọ́, ati ki ẹnyin ki o le mã sin Oluwa laisi ìyapa-ọkàn.

Ka pipe ipin 1. Kor 7