Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Kor 4:6-21 Yorùbá Bibeli (YCE)

6. Njẹ ará, nkan wọnyi ni mo ti fi ṣe apẹrẹ ara mi ati Apollo nitori nyin; ki ẹnyin ki o le ti ipa wa kọ́ ki ẹ maṣe ré ohun ti a ti kọwe rẹ̀ kọja, ki ẹnikan ninu nyin ki o máṣe ti itori ẹnikan gberaga si ẹnikeji.

7. Nitori tali o mu ọ yàtọ? kini iwọ si ní ti iwọ kò ti gbà? njẹ bi iwọ ba si ti gbà a, éhatiṣe ti iwọ fi nhalẹ, bi ẹnipe iwọ kò gbà a?

8. A sá tẹ́ nyin lọrùn nisisiyi, a sá ti sọ nyin di ọlọrọ̀ nisisiyi, ẹnyin ti njọba laisi wa: iba si wu mi ki ẹnyin ki o jọba, ki awa ki o le jùmọ jọba pẹlu nyin.

9. Nitori mo rò pe Ọlọrun ti yan awa Aposteli kẹhin bi awọn ẹniti a dalẹbi ikú: nitoriti a fi wa ṣe iran wò fun aiye, ati fun angẹli, ati fun enia.

10. Awa jẹ aṣiwere nitori Kristi, ṣugbọn ẹnyin jẹ ọlọgbọ́n ninu Kristi; awa jẹ alailera, ṣugbọn ẹnyin jẹ alagbara; ẹnyin jẹ ọlọlá, ṣugbọn awa jẹ ẹni ẹ̀gan.

11. Ani titi fi di wakati yi li ebi npa wa, ti òrungbẹ si ngbẹ wa, ti a si wà ni ìhoho, ti a si nlù wa, ti a kò si ni ibugbé kan;

12. Ti a nṣe lãlã, a nfi ọwọ́ ara wa ṣiṣẹ: nwọn ngàn wa, awa nsure; nwọn nṣe inunibini si wa, awa nforitì i:

13. Nwọn nkẹgàn wa, awa mbẹ̀bẹ: a ṣe wa bi ohun ẹgbin aiye, bi ẽri ohun gbogbo titi di isisiyi.

14. Emi kò kọ̀we nkan wọnyi lati fi dojutì nyin, ṣugbọn lati kìlọ fun nyin bi awọn ọmọ mi ayanfẹ.

15. Nitori bi ẹnyin tilẹ ni ẹgbarun olukọni ninu Kristi, ṣugbọn ẹnyin kò ni baba pipọ: nitoripe ninu Kristi Jesu ni mo ti fi ihinrere bí nyin.

16. Nitorina mo bẹ̀ nyin, ẹ mã ṣe afarawe mi.

17. Nitorina ni mo ṣe rán Timotiu si nyin, ẹniti iṣe ọmọ mi olufẹ ati olododo ninu Oluwa, ẹniti yio ma mu nyin ranti ọ̀na mi ti o wà ninu Kristi, gẹgẹ bi mo ti nkọ́ni ninu gbogbo ijọ nibigbogbo.

18. Ṣugbọn awọn ẹlomiran gberaga ninu nyin, bi ẹnipe emi kì yio tọ̀ nyin wá mọ́.

19. Ṣugbọn emi ó tọ̀ nyin wá ni lọ̃lọ yi, bi Oluwa ba fẹ; kì si iṣe ọ̀rọ awọn ti ngberaga li emi o mọ̀, bikoṣe agbara.

20. Nitori ijọba Ọlọrun kì iṣe ninu ọ̀rọ, bikoṣe ninu agbara.

21. Kili ẹnyin nfẹ? emi ó ha tọ̀ nyin wá ti emi ti kùmọ bi, tabi ni ifẹ, ati ẹmí inututù?

Ka pipe ipin 1. Kor 4