Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Gal 2:15-21 Yorùbá Bibeli (YCE)

15. Awa ti iṣe Ju nipa ẹda, ti kì si iṣe ẹlẹṣẹ ti awọn Keferi,

16. Ti a mọ̀ pe a ko da ẹnikẹni lare nipa iṣẹ ofin, bikoṣe nipa igbagbọ́ ninu Jesu Kristi, ani awa na gbà Jesu Kristi gbọ́, ki a ba le da wa lare nipa igbagbọ́ ti Kristi, kì si iṣe nipa iṣẹ ofin: nitoripe nipa iṣẹ ofin kò si enia kan ti a o dalare.

17. Ṣugbọn nigbati awa ba nwá ọ̀na lati ri idalare nipa Kristi, bi a ba si ri awa tikarawa li ẹlẹṣẹ, njẹ́ Kristi ha nṣe iranṣẹ ẹ̀ṣẹ bi? Ki a má ri.

18. Nitoripe bi mo ba si tun gbe ohun wọnni ti mo ti wó palẹ ró, mo fi ara mi han bi arufin.

19. Nitoripe nipa ofin mo ti di oku si ofin, ki emi ki o le wà lãye si Ọlọrun.

20. A ti kàn mi mọ agbelebu pẹlu Kristi: ṣugbọn mo wà lãye, sibẹ ki iṣe emi mọ́, ṣugbọn Kristi wà lãye ninu mi: wiwà ti mo si wà lãye ninu ara, mo wa lãye ninu igbagbọ Ọmọ Ọlọrun, ẹniti o fẹ mi, ti o si fi on tikararẹ̀ fun mi.

21. Emi kò sọ ore-ọfẹ Ọlọrun di asan: nitoripe bi ododo ba ti ipa ofin wá, njẹ Kristi kú lasan.

Ka pipe ipin Gal 2