Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sek 10:1-8 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. Ẹ bère òjo nigba arọ̀kuro li ọwọ Oluwa; Oluwa yio kọ mànamána, yio si fi ọ̀pọ òjò fun wọn, fun olukulukù koriko ni pápa.

2. Nitori awọn oriṣa ti nsọ̀rọ asan, awọn alafọṣẹ si ti ri eké, nwọn si ti rọ́ alá eké; nwọn ntù ni ni inu lasan, nitorina nwọn ba ti wọn lọ bi ọwọ́ ẹran, a ṣẹ wọn niṣẹ, nitori darandaran kò si.

3. Ibinu mi ru si awọn darandaran, mo si jẹ awọn ewurẹ ni iyà; nitori Oluwa awọn ọmọ-ogun ti bẹ̀ agbo rẹ̀ ile Juda wò, o si fi wọn ṣe bi ẹṣin rẹ̀ daradara li ogun.

4. Lati ọdọ rẹ̀ ni igun ti jade wá, lati ọdọ rẹ̀ ni iṣo ti wá, lati ọdọ rẹ̀ ni ọrun ogun ti wá, lati ọdọ rẹ̀ ni awọn akoniṣiṣẹ gbogbo ti wá.

5. Nwọn o si dabi awọn alagbara, ti ntẹ́ ẹrẹ̀ ita ni mọlẹ li ogun: nwọn o si jagun, nitori Oluwa wà pẹlu wọn nwọn o si doju tì awọn ti ngùn ẹṣin.

6. Emi o si mu ile Juda le, emi o si gbà ile Josefu là, emi o si tún mu wọn joko; nitori mo ti ṣãnu fun wọn, nwọn o si dabi ẹnipe emi kò ti ta wọn nù: nitori emi ni Oluwa Ọlọrun wọn, emi o si gbọ́ ti wọn.

7. Efraimu yio si ṣe bi alagbara, ọkàn wọn yio si yọ̀ bi ẹnipe nipa ọti-waini: ani awọn ọmọ wọn yio ri i, nwọn o si yọ̀, inu wọn o si dùn si Oluwa.

8. Emi o kọ si wọn, emi o si ṣà wọn jọ; nitori emi ti rà wọn pada: nwọn o si rẹ̀ si i gẹgẹ bi wọn ti nrẹ̀ si i ri.

Ka pipe ipin Sek 10