Nwọn o si dabi awọn alagbara, ti ntẹ́ ẹrẹ̀ ita ni mọlẹ li ogun: nwọn o si jagun, nitori Oluwa wà pẹlu wọn nwọn o si doju tì awọn ti ngùn ẹṣin.