1. OLUWA si sọ fun Mose pe,
2. Fi aṣẹ fun awọn ọmọ Israeli, ki o si wi fun wọn pe, Ọrẹ-ẹbọ mi, ati àkara mi fun ẹbọ mi ti a fi iná ṣe, fun õrùn didùn si mi, ni ki ẹnyin ma kiyesi lati mú fun mi wá li akokò wọn.
3. Ki iwọ ki o si wi fun wọn pe, Eyi li ẹbọ ti a fi iná ṣe, ti ẹnyin o ma múwa fun OLUWA, akọ ọdọ-agutan meji ọlọdún kan alailabùku li ojojumọ́, fun ẹbọ sisun igbagbogbo.
4. Ọdọ-agutan kan ni ki iwọ ki o fi rubọ li owurọ̀, ati ọdọ-agutan keji ni ki iwọ ki o fi rubọ li aṣalẹ;
5. Ati idamẹwa òṣuwọn efa iyẹfun fun ẹbọ ohunjijẹ, ti a fi idamẹrin òṣuwọn hini oróro gigún pò.
6. Ẹbọ sisun igbagbogbo ni, ti a ti lanasilẹ li òke Sinai fun õrùn didùn, ẹbọ ti a fi iná ṣe si OLUWA.
7. Ati ẹbọ ohunmimu rẹ̀ ki o jẹ́ idamẹrin òṣuwọn hini fun ọdọ-agutan kan: ni ibi-mimọ ni ki iwọ da ọti lile nì silẹ fun OLUWA fun ẹbọ ohunmimu.
8. Ọdọ-agutan keji ni ki iwọ ki o fi rubọ li aṣalẹ: bi ẹbọ ohunjijẹ ti owurọ̀, ati bi ẹbọ ohunmimu rẹ̀ ni ki iwọ ki o ṣe, ẹbọ ti a fi iná ṣe, õrùn didùn si OLUWA.
9. Ati li ọjọ́-isimi akọ ọdọ-agutan meji ọlọdún kan alailabùku, ati idamẹwa meji òṣuwọn iyẹfun fun ẹbọ ohunjijẹ, ti a fi oróro pò, ati ẹbọ ohunmimu rẹ̀:
10. Eyi li ẹbọ sisun ọjọjọ́ isimi, pẹlu ẹbọ sisun igbagbogbo, ati ẹbọ ohunmimu rẹ̀.
11. Ati ni ìbẹrẹ òṣu nyin ki ẹnyin ki o ru ẹbọ sisun kan si OLUWA; ẹgbọrọ akọmalu meji, ati àgbo kan, akọ ọdọ-agutan meje ọlọdún kan alailabùku;
12. Ati idamẹwa mẹta òṣuwọn iyẹfun, ti a fi oróro pò, fun akọmalu kan, fun ẹbọ ohunjijẹ; ati idamẹwa meji òṣuwọn iyẹfun, ti a fi oróro pò, fun àgbo kan, fun ẹbọ ohunjijẹ:
13. Ati idamẹwa òṣuwọn iyẹfun, ti a fi oróro pò, fun ọdọ-agutan kan fun ẹbọ ohunjijẹ; fun ẹbọ sisun õrùn didùn, ẹbọ ti a fi iná ṣe si OLUWA.
14. Ki ẹbọ ohunmimu wọn ki o jẹ́ àbọ òṣuwọn hini ti ọti-waini fun akọmalu kan, ati idamẹta òṣuwọn hini fun àgbo kan, ati idamẹrin òṣuwọn hini fun ọdọ-agutan kan: eyi li ẹbọ sisun oṣuṣù ni gbogbo oṣù ọdún.
15. A o si fi obukọ kan ru ẹbọ ẹ̀ṣẹ si OLUWA; pẹlu ẹbọ sisun igbagbogbo, ati ẹbọ ohunmimu rẹ̀.
16. Ati li ọjọ́ kẹrinla oṣù kini, ni irekọja OLUWA.
17. Ati li ọjọ́ kẹdogun oṣù na yi li ajọ: ni ijọ́ meje ni ki a fi jẹ àkara alaiwu.
18. Li ọjọ́ kini ki apejọ mimọ́ ki o wà; ẹnyin kò gbọdọ ṣe iṣẹ agbara kan:
19. Ṣugbọn ki ẹnyin ki o ru ẹbọ kan ti a fi iná ṣe, ẹbọ sisun si OLUWA; ẹgbọrọ akọmalu meji, ati àgbo kan, ati akọ ọdọ-agutan meje ọlọdun kan: ki nwọn ki o jẹ́ alailabùku fun nyin.
20. Ẹbọ ohunjijẹ wọn iyẹfun ti a fi oróro pò, idamẹwa mẹta òṣuwọn ni ki ẹnyin ki o múwa fun akọmalu kan, ati idamẹwa meji òṣuwọn fun àgbo na.
21. Ati idamẹwa òṣuwọn ni ki iwọ ki o múwa fun ọdọ-agutan kan, fun gbogbo ọdọ-agutan mejeje;
22. Ati obukọ kan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ, lati ṣètutu fun nyin.
23. Ki ẹnyin ki o mú wọnyi wá pẹlu ẹbọ sisun owurọ̀, ti iṣe ti ẹbọ sisun igbagbogbo.
24. Bayi ni ki ẹnyin rubọ li ọjọjọ́, jalẹ ni ijọ́ mejeje, onjẹ ẹbọ ti a fi iná ṣe, ti õrùn didùn si OLUWA: ki a ru u pẹlu ẹbọ sisun igbagbogbo, ati ẹbọ ohunmimu rẹ̀.
25. Ati ni ijọ́ keje ki ẹnyin ki o ní apejọ mimọ́; ẹnyin kò gbọdọ ṣe iṣẹ agbara kan.
26. Li ọjọ́ akọ́so pẹlu, nigbati ẹnyin ba mú ẹbọ ohunjijẹ titun wá fun OLUWA, lẹhin ọsẹ̀ nyin wọnni, ki ẹnyin ki o ní apejọ mimọ́; ẹnyin kò gbọdọ ṣe iṣẹ agbara kan:
27. Ṣugbọn ki ẹnyin ki o fi ẹgbọrọ akọmalu meji, àgbo kan, akọ ọdọ-agutan meje ọlọdún kan, ru ẹbọ sisun fun õrùn didùn si OLUWA;
28. Ati ẹbọ ohunjijẹ wọn, iyẹfun ti a fi oróro pò, idamẹwa mẹta òṣuwọn fun akọmalu kan, ati idamẹwa meji òṣuwọn fun àgbo kan,
29. Ati idamẹwa òṣuwọn fun ọdọ-agutan kan, bẹ̃ni fun ọdọ-agutan mejeje;
30. Ati obukọ kan, lati ṣètutu fun nyin.
31. Ki ẹnyin ki o ru wọn pẹlu ẹbọ sisun igba-gbogbo, ati ẹbọ ohunjijẹ rẹ̀ (ki nwọn ki o jẹ́ alailabùku fun nyin), ati ẹbọ ohunmimu wọn.