Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Num 22:31-41 Yorùbá Bibeli (YCE)

31. Nigbana ni OLUWA là Balaamu li oju, o si ri angeli OLUWA duro loju ọ̀na, idà rẹ̀ fifàyọ si wà li ọwọ́ rẹ̀: o si tẹ̀ ori ba, o si doju rẹ̀ bolẹ.

32. Angeli OLUWA si wi fun u pe, Ẽṣe ti iwọ fi lù kẹtẹkẹtẹ rẹ ni ìgba mẹta yi? Kiyesi i, emi jade wá lati di ọ lọ̀na, nitori ọ̀na rẹ lòdi niwaju mi.

33. Kẹtẹkẹtẹ na si ri mi, o si yà fun mi ni ìgba mẹta yi: bikoṣe bi o ti yà fun mi, pipa ni emi iba pa ọ, emi a si dá on si.

34. Balaamu si wi fun angeli OLUWA pe, Emi ti ṣẹ̀; nitori emi kò mọ̀ pe iwọ duro dè mi li ọ̀na; njẹ bi kò ba ṣe didùn inu rẹ, emi o pada.

35. Angeli OLUWA si wi fun Balaamu pe, Ma bá awọn ọkunrin na lọ: ṣugbọn kìki ọ̀rọ ti emi o sọ fun ọ, eyinì ni ki iwọ ki o sọ. Bẹ̃ni Balaamu bá awọn ijoye Balaki lọ.

36. Nigbati Balaki gbọ́ pe Balaamu dé, o jade lọ ipade rẹ̀ si Ilu Moabu, ti mbẹ ni àgbegbe Arnoni, ti iṣe ipẹkun ipinlẹ na.

37. Balaki si wi fun Balaamu pe, Emi kò ha ranṣẹ kanjukanju si ọ lati pè ọ? ẽṣe ti iwọ kò fi tọ̀ mi wá? emi kò ha to lati sọ ọ di ẹni nla?

38. Balaamu si wi fun Balaki pe, Kiyesi i, emi tọ̀ ọ wá: emi ha lí agbara kan nisisiyi rára lati wi ohun kan? ọ̀rọ ti OLUWA fi si mi li ẹnu, on li emi o sọ.

39. Balaamu si bá Balaki lọ, nwọn si wá si Kiriati-husotu.

40. Balaki si rubọ akọmalu ati agutan, o si ranṣẹ si Balaamu, ati si awọn ijoye ti mbẹ pẹlu rẹ̀.

41. O si ṣe ni ijọ́ keji, ni Balaki mú Balaamu, o si mú u wá si ibi giga Baali, ki o ba le ri apakan awọn enia na lati ibẹ̀ lọ.

Ka pipe ipin Num 22