Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Num 21:2-22 Yorùbá Bibeli (YCE)

2. Israeli si jẹ́ ẹjẹ́ fun OLUWA, wipe, Bi iwọ ba fi awọn enia yi lé mi lọwọ nitõtọ, njẹ emi o run ilu wọn patapata.

3. OLUWA si gbọ́ ohùn Israeli, o si fi awọn ara Kenaani tọrẹ, nwọn si run wọn patapata, ati ilu wọn: o si sọ orukọ ibẹ̀ na ni Horma.

4. Nwọn si rìn lati òke Hori lọ li ọ̀na Okun Pupa, lati yi ilẹ Edomu ká: sũru si tán awọn enia na pupọ̀pupọ nitori ọ̀na na.

5. Awọn enia na si bá Ọlọrun, ati Mose sọ̀ pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi mú wa gòke lati Egipti jade wá lati kú li aginjù? nitoripe àkara kò sí, bẹ̃ni kò sí omi; onjẹ futẹfutẹ yi si sú ọkàn wa.

6. OLUWA si rán ejò amubina si awọn enia na, nwọn si bù awọn enia na ṣan; ọ̀pọlọpọ ninu Israeli si kú.

7. Nitorina li awọn enia na ṣe tọ̀ Mose wá, nwọn si wipe, Awa ti ṣẹ̀, nitoriti awa ti bá OLUWA ati iwọ sọ̀; gbadura si OLUWA ki o mú ejò wọnyi kuro lọdọ wa. Mose si gbadura fun awọn enia na.

8. OLUWA si wi fun Mose pe, Rọ ejò amubina kan, ki o si fi i sori ọpá-gigùn kan: yio si ṣe, olukuluku ẹniti ejò ba bùṣan, nigbati o ba wò o, yio yè.

9. Mose si rọ ejò idẹ kan, o si fi i sori ọpá-gigùn na: o si ṣe, pe bi ejò kan ba bù enia kan ṣan, nigbati o ba wò ejò idẹ na, on a yè.

10. Awọn ọmọ Israeli si ṣi siwaju, nwọn si dó ni Obotu.

11. Nwọn si ṣi lati Obotu lọ, nwọn si dó si Iye-abarimu, li aginjù ti mbẹ niwaju Moabu, ni ìha ìla-õrùn.

12. Lati ibẹ̀ lọ nwọn ṣí, nwọn si dó si afonifoji Seredi.

13. Lati ibẹ̀ lọ nwọn ṣí, nwọn si dó si ìha keji Arnoni, ti mbẹ li aginjù, ti o ti àgbegbe awọn ọmọ Amori wá: nitoripe Arnoni ni ipinlẹ Moabu, lãrin Moabu ati awọn Amori.

14. Nitorina ni a ṣe wi ninu iwé Ogun OLUWA pe, Ohun ti o ṣe li Okun Pupa, ati li odò Arnoni.

15. Ati ni iṣàn-odò nì ti o darí si ibujoko Ari, ti o si gbè ipinlẹ Moabu.

16. Lati ibẹ̀ nwọn si lọ si Beeri: eyinì ni kanga eyiti OLUWA sọ fun Mose pe, Pe awọn enia jọ, emi o si fun wọn li omi.

17. Nigbana ni Israeli kọrin yi pe: Sun jade iwọ kanga; ẹ ma kọrin si i:

18. Kanga na, ti awọn olori wà, ti awọn ọlọlá awọn enia si fi ọpá-alade na, ati ọpá wọn wà. Ati lati aginjù na, nwọn lọ si Mattana.

19. Ati Mattana nwọn lọ si Nahalieli: ati lati Nahalieli nwọn lọ si Bamotu:

20. Ati lati Bamotu li afonifoji nì, ti mbẹ ni ilẹ Moabu, si óke Pisga, ti o si kọjusi aginjù.

21. Israeli si rán onṣẹ si Sihoni ọba awọn ọmọ Amori, wipe,

22. Jẹ ki emi là ilẹ rẹ kọja lọ: awa ki yio yà sinu oko, tabi ọgba-àjara; awa ki yio mu ninu omi kanga: ọ̀na opópo ọba li a o gbà, titi awa o fi kọja ipinlẹ rẹ.

Ka pipe ipin Num 21