Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Num 20:9-27 Yorùbá Bibeli (YCE)

9. Mose si mú ọpá na lati iwaju OLUWA lọ, bi o ti fun u li aṣẹ.

10. Mose ati Aaroni si pe ijọ awọn enia jọ niwaju apata na, o si wi fun wọn pe, Ẹnyin gbọ̀ nisisiyi, ẹnyin ọlọtẹ; ki awa ki o ha mú omi lati inu apata yi fun nyin wá bi?

11. Mose si gbé ọwọ́ rẹ̀ soke, o si fi ọpá rẹ̀ lù apata na lẹ̃meji: omi si tú jade li ọ̀pọlọpọ, ijọ awọn enia si mu, ati ẹran wọn pẹlu.

12. OLUWA si sọ fun Mose ati fun Aaroni pe, Nitoriti ẹnyin kò gbà mi gbọ́, lati yà mi simimọ́ loju awọn ọmọ Israeli, nitorina ẹnyin ki yio mú ijọ awọn enia yi lọ si ilẹ na ti mo fi fun wọn.

13. Wọnyi li omi Meriba; nitoriti awọn ọmọ Israeli bá OLUWA sọ̀, o si di ẹni ìya-simimọ́ ninu wọn.

14. Mose si rán onṣẹ lati Kadeṣi si ọba Edomu, wipe, Bayi ni Israeli arakunrin rẹ wi, Iwọ sá mọ̀ gbogbo ìrin ti o bá wa:

15. Bi awọn baba wa ti sọkalẹ lọ si Egipti, ti awa si ti gbé Egipti ni ìgba pipẹ; awọn ara Egipti si ni wa lara, ati awọn baba wa:

16. Nigbati awa si kepè OLUWA, o gbọ́ ohùn wa, o si rán angeli kan, o si mú wa lati Egipti jade wá; si kiyesi i, awa mbẹ ni Kadeṣi, ilu kan ni ipinlẹ àgbegbe rẹ:

17. Jẹ ki awa ki o là ilẹ rẹ kọja lọ, awa bẹ̀ ọ: awa ki yio là inu oko rẹ, tabi inu ọgbà-àjara, bẹ̃li awa ki yio mu ninu omi kanga: ọ̀na opópo ọba li awa o gbà, awa ki o yà si ọwọ́ ọtún tabi si òsi, titi awa o fi kọja ipinlẹ rẹ.

18. Edomu si wi fun u pe, Iwọ ki yio kọja lọdọ mi, ki emi ki o má ba jade si ọ ti emi ti idà.

19. Awọn ọmọ Israeli si wi fun u pe, Ọ̀na opópo ọba li awa o gbà: bi awa ba mu ninu omi rẹ, emi ati ẹran mi, njẹ emi o san owo rẹ̀: laiṣe ohun miran, ki nsá fi ẹsẹ̀ mi là ilẹ kọja.

20. O si wipe, Iwọ ki yio là ilẹ kọja. Edomu si mú ọ̀pọ enia jade tọ̀ ọ wá pẹlu ọwọ́ agbara.

21. Bẹ̃li Edomu kọ̀ lati fi ọ̀na fun Israeli li àgbegbe rẹ̀: Israeli si ṣẹri kuro lọdọ rẹ̀.

22. Awọn ọmọ Israeli, ani gbogbo ijọ si ṣí kuro ni Kadeṣi, nwọn si wá si òke Hori.

23. OLUWA si sọ fun Mose ati fun Aaroni li òke Hori li àgbegbe ilẹ Edomu wipe,

24. A o kó Aaroni jọ pẹlu awọn enia rẹ̀: nitoripe on ki yio wọ̀ inu ilẹ na ti mo fi fun awọn ọmọ Israeli, nitoriti ẹnyin ṣọ̀tẹ si aṣẹ mi, nibi omi Meriba.

25. Mú Aaroni ati Eleasari ọmọ rẹ̀, ki o si mú wọn wá si ori-òke Hori:

26. Ki o si bọ́ Aaroni li aṣọ rẹ̀, ki o si fi wọn wọ̀ Eleasari ọmọ rẹ̀: a o si kó Aaroni jọ pẹlu awọn enia rẹ̀, yio si kú nibẹ̀.

27. Mose si ṣe bi OLUWA ti fun u li aṣẹ: nwọn si gòke lọ si ori òke Hori li oju gbogbo ijọ.

Ka pipe ipin Num 20