Mose si bọ́ Aaroni li aṣọ rẹ̀, o si fi wọn wọ̀ Eleasari ọmọ rẹ̀; Aaroni si kú nibẹ̀ li ori òke na: Mose ati Eleasari si sọkalẹ lati ori òke na wá.