Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Neh 9:6-15 Yorùbá Bibeli (YCE)

6. Iwọ, ani iwọ nikanṣoṣo li Oluwa; iwọ li o ti dá ọrun, ọrun awọn ọrun pẹlu gbogbo ogun wọn, aiye, ati ohun gbogbo ti mbẹ ninu rẹ̀, okun, ati ohun gbogbo ti mbẹ̀ ninu rẹ̀, iwọ si pa gbogbo wọn mọ́ lãyè, ogun ọrun si nsìn ọ.

7. Iwọ ni Oluwa Ọlọrun, ti o ti yan Abramu, ti o si mu u jade lati Uri ti Kaldea wá, iwọ si sọ orukọ rẹ̀ ni Abrahamu;

8. Iwọ si ri pe ọkàn rẹ̀ jẹ olõtọ niwaju rẹ, iwọ si ba a dá majẹmu lati fi ilẹ awọn ara Kenaani, awọn ara Hitti, awọn ara Amori, ati awọn ara Perisi, ati awọn ara Jebusi, ati awọn ara Girgasi fun u, lati fi fun iru-ọmọ rẹ̀, iwọ si ti mu ọ̀rọ rẹ ṣẹ; nitori olododo ni iwọ:

9. Iwọ si ri ipọnju awọn baba wa ni Egipti, o si gbọ́ igbe wọn lẹba Okun Pupa;

10. O si fi ami, ati iṣẹ-iyanu hàn li ara Farao, ati li ara gbogbo iranṣẹ rẹ̀, ati li ara gbogbo enia ilẹ rẹ̀: nitori iwọ mọ̀ pe, nwọn hu ìwa igberaga si wọn. Iwọ si fi orukọ fun ara rẹ bi ti oni yi.

11. Iwọ si ti pin okun niwaju wọn, nwọn si la arin okun ja li ori ilẹ gbigbẹ; iwọ sọ awọn oninunibini wọn sinu ibú, bi okuta sinu omi lile.

12. Iwọ si fi ọwọ̀n awọ-sanma ṣe amọ̀na wọn li ọsan, ati li oru, ọwọ̀n iná, lati fun wọn ni imọlẹ li ọ̀na ninu eyiti nwọn o rin.

13. Iwọ si sọkalẹ wá si ori òke Sinai, o si bá wọn sọ̀rọ lati ọrun wá, o fun wọn ni idajọ titọ, ofin otitọ, ilana ati ofin rere.

14. Iwọ si mu ọjọ isimi mimọ rẹ di mimọ̀ fun wọn, o si paṣẹ ẹkọ́, ilana, ati ofin fun wọn, nipa ọwọ Mose iranṣẹ rẹ.

15. O si fun wọn li onjẹ lati ọrun wá fun ebi wọn, o si mu omi lati inu apata wá fun orungbẹ wọn, o si ṣe ileri fun wọn pe, ki nwọn lọ ijogun ilẹ na ti iwọ ti bura lati fi fun wọn.

Ka pipe ipin Neh 9