Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Neh 3:1-13 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. NIGBANA ni Eliaṣibu olori alufa dide pẹlu awọn alufa arakunrin rẹ̀, nwọn si mọ ẹnu-bode agutan; nwọn sọ ọ di mimọ́, nwọn si gbe ilẹkùn rẹ̀ duro, titi de ile-iṣọ Mea, ni nwọn sọ di mimọ́ titi de ile-iṣọ Hananeeli.

2. Lọwọkọwọ rẹ̀ ni awọn ọkunrin Jeriko si mọ: lọwọkọwọ wọn ni Sakkuri ọmọ Imri si mọ.

3. Ṣugbọn ẹnu-bode Ẹja ni awọn ọmọ Hasenaa mọ, ẹniti o tẹ́ igi idabu rẹ̀, ti o si gbe ilẹkun rẹ̀ ro, àgadágodo rẹ̀, ati itikùn rẹ̀.

4. Lọwọkọwọ wọn ni Meremoti ọmọ Urijah, ọmọ Kosi, tun ṣe. Ati lọwọkọwọ wọn ni Meṣullamu, ọmọ Berekiah, ọmọ Meṣesabeli tun ṣe. Ati lọwọkọwọ wọn ni Sadoku, ọmọ Baana tun ṣe.

5. Ati lọwọkọwọ wọn ni awọn ará Tekoa tun ṣe, ṣugbọn awọn ọlọla kò fi ọrùn si iṣẹ Oluwa wọn.

6. Jehoida, ọmọ Pasea, ati Meṣullamu, ọmọ Besodiah, si tun ẹnu-bode atijọ ṣe, nwọn tẹ̀ igi idabu rẹ̀, nwọn si gbe ilẹkùn rẹ̀ ro, ati àgadágodo rẹ̀, ati itikùn rẹ̀.

7. Lọwọkọwọ wọn ni Melatiah, ará Gibeoni, tun ṣe, ati Jadoni, ara Merono, awọn ọkunrin ti Gibeoni, ati ti Mispa, ti o jẹ ti itẹ bãlẹ̀ apa ihin odò.

8. Lọwọkọwọ rẹ̀ ni Ussieli ọmọ Harhiah, alagbẹdẹ wura tun ṣe; ati lọwọkọwọ rẹ̀ ni Hananiah ọmọ alapolu, tun ṣe; nwọn si ti fi Jerusalemu silẹ̀ titi de odi gbigbõro.

9. Lọwọkọwọ wọn ni Refaiah, ọmọ Huri ijòye idaji Jerusalemu si tun ṣe.

10. Lọwọkọwọ wọn ni Jedaiah, ọmọ Haramafu, si tun ṣe, ani ọkánkan ile rẹ̀. Lọwọkọwọ rẹ̀ ni Hattuṣi ọmọ Haṣabaniah si tun ṣe.

11. Malkijah ọmọ Harimu, ati Haṣubu ọmọ Pahati-Moabu, tun apa keji ṣe, ati ile-iṣọ ileru.

12. Ati lọwọkọwọ rẹ̀ Ṣallumu ọmọ Haloheṣi, ijòye apa kan Jerusalemu, tun ṣe, on ati awọn ọmọbinrin rẹ̀.

13. Hanuni pẹlu awọn ará Sanoa si tun ẹnu-bode afonifoji ṣe; nwọn kọ́ ọ, nwọn si gbe ilẹkùn rẹ̀ ro, àgadágodo rẹ̀ ati itikùn rẹ̀, ati ẹgbẹrun igbọnwọ odi titi de ẹnu-bode ãtàn.

Ka pipe ipin Neh 3