Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lef 9:1-17 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. O si ṣe ni ijọ́ kẹjọ, ni Mose pè Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀, ati awọn àgba Israeli;

2. O si wi fun Aaroni pe, Mú ọmọ akọmalu kan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ati àgbo kan alailabùku fun ẹbọ sisun, ki o fi wọn rubọ niwaju OLUWA.

3. Ki iwọ ki o si sọ fun awọn ọmọ Israeli pe, Ẹ mú obukọ kan wá fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ; ati ọmọ malu kan, ati ọdọ-agutan kan, mejeji ọlọdún kan, alailabùku, fun ẹbọ sisun;

4. Ati akọmalu kan ati àgbo kan fun ẹbọ alafia, lati fi ru ẹbọ niwaju OLUWA; ati ẹbọ ohunjijẹ ti a fi oróro pò: nitoripe li oni li OLUWA yio farahàn nyin.

5. Nwọn si mú ohun ti Mose filelẹ li aṣẹ́ wá siwaju agọ́ ajọ: gbogbo ijọ si sunmọtosi nwọn si duro niwaju OLUWA.

6. Mose si wipe, Eyi li ohun ti OLUWA filelẹ li aṣẹ, ki ẹnyin ki o ṣe: ogo OLUWA yio si farahàn nyin.

7. Mose si sọ fun Aaroni pe, Sunmọ pẹpẹ, ki o si ru ẹbọ ẹ̀ṣẹ rẹ, ati ẹbọ sisun rẹ, ki o si ṣètutu fun ara rẹ, ati fun awọn enia: ki o si ru ọrẹ-ẹbọ awọn enia, ki o si ṣètutu fun wọn; bi OLUWA ti fi aṣẹ lelẹ.

8. Aaroni si sunmọ pẹpẹ, o si pa ọmọ malu ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ti iṣe ti on tikalarẹ̀.

9. Awọn ọmọ Aaroni si mú ẹ̀jẹ na tọ̀ ọ wá: o si tẹ̀ iká rẹ̀ bọ̀ inu ẹ̀jẹ na, o si tọ́ ọ sara iwo pẹpẹ, o si dà ẹ̀jẹ na si isalẹ pẹpẹ:

10. Ṣugbọn ọrá, ati iwe, ati àwọn ti o bò ẹ̀dọ ti ẹbọ ẹ̀ṣẹ, o sun u lori pẹpẹ; bi OLUWA ti fi aṣẹ fun Mose.

11. Ati ẹran ati awọ li o fi iná sun lẹhin ibudó.

12. O si pa ẹbọ sisun: awọn ọmọ Aaroni si mú ẹ̀jẹ rẹ̀ tọ̀ ọ wá, o si fi i wọ́n ori pẹpẹ yiká.

13. Nwọn si mú ẹbọ sisun tọ̀ ọ wá, ti on ti ipín rẹ̀, ati ori: o si sun wọn lori pẹpẹ.

14. O si ṣìn ifun ati itan rẹ̀, o si sun wọn li ẹbọ sisun lori pẹpẹ.

15. O si mú ọrẹ-ẹbọ awọn enia wá, o si mú obukọ, ti iṣe ẹbọ ẹ̀ṣẹ fun awọn enia, o si pa a, o si fi i rubọ ẹ̀ṣẹ, bi ti iṣaju.

16. O si mú ẹbọ sisun wá, o si ru u gẹgẹ bi ìlana na.

17. O si mú ẹbọ ohunjijẹ wá, o si bù ikunwọ kan ninu rẹ̀, o si sun u lori pẹpẹ, pẹlu ẹbọ sisun owurọ̀.

Ka pipe ipin Lef 9