Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lef 26:41-44 Yorùbá Bibeli (YCE)

41. Emi pẹlu rìn lodi si wọn, mo si mú wọn wá si ilẹ awọn ọtá wọn: njẹ bi àiya wọn alaikọlà ba rẹ̀silẹ, ti nwọn ba si gbà ibawi ẹ̀ṣẹ wọn;

42. Nigbana li emi o ranti majẹmu mi pẹlu Jakobu; ati majẹmu mi pẹlu Isaaki, ati majẹmu mi pẹlu Abrahamu li emi o ranti; emi o si ranti ilẹ na.

43. Nwọn o si fi ilẹ na silẹ, on o si ní isimi rẹ̀, nigbati o ba di ahoro li aisí wọn; nwọn o si gbà ibawi ẹ̀ṣẹ wọn: nitoripe, ani nitoripe nwọn gàn idajọ mi, ati ọkàn wọn korira ìlana mi.

44. Ṣugbọn sibẹ̀ ninu gbogbo eyina, nigbati nwọn ba wà ni ilẹ awọn ọtá wọn, emi ki yio tà wọn nù, bẹ̃li emi ki yio korira wọn, lati run wọn patapata, ati lati dà majẹmu mi pẹlu wọn: nitoripe Emi li OLUWA Ọlọrun wọn:

Ka pipe ipin Lef 26