Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lef 22:1-12 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. OLUWA si sọ fun Mose pe,

2. Sọ fun Aaroni ati fun awọn ọmọ rẹ̀ pe, ki nwọn ki o yà ara wọn sọ̀tọ kuro ninu ohun mimọ́ awọn ọmọ Israeli, ki nwọn ki o má si ṣe bà orukọ mimọ́ mi jẹ́ ninu ohun wọnni, ti nwọn yàsimimọ́ fun mi: Emi li OLUWA,

3. Wi fun wọn pe, Ẹnikẹni ninu gbogbo irú-ọmọ nyin ninu awọn iran nyin, ti o ba sunmọ ohun mimọ́, ti awọn ọmọ Israeli yàsimimọ́ fun OLUWA, ti o ní aimọ́ rẹ̀ lara rẹ̀, ọkàn na li a o ke kuro niwaju mi: Emi li OLUWA.

4. Ẹnikẹni ninu irú-ọmọ Aaroni ti iṣe adẹtẹ, tabi ti o ní isun; ki o máṣe jẹ ninu ohun mimọ́, titi on o fi di mimọ́. Ati ẹnikẹni ti o farakàn ohun ti iṣe aimọ́, bi okú, tabi ọkunrin ti ohun-irú nti ara rẹ̀ jade;

5. Tabi ẹniti o ba farakàn ohun ti nrakò kan, ti yio sọ ọ di aimọ́, tabi enia kan ti yio sọ ọ di aimọ́, irú aimọ́ ti o wù ki o ní;

6. Ọkàn ti o ba farakàn ọkan ninu irú ohun bẹ̃ ki o jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ, ki o má si ṣe jẹ ninu ohun mimọ́, bikoṣepe o ba fi omi wẹ̀ ara rẹ̀.

7. Nigbati õrùn ba si wọ̀, on o di mimọ́; lẹhin eyinì ki o si ma jẹ ninu ohun mimọ́, nitoripe onjẹ rẹ̀ ni.

8. On kò gbọdọ jẹ ẹran ti o kú fun ara rẹ̀, tabi eyiti ẹranko fàya, lati fi i bà ara rẹ̀ jẹ́: Emi li OLUWA.

9. Nitorina ki nwọn ki o ma pa ìlana mi mọ́, ki nwọn ki o máṣe rù ẹ̀ṣẹ nitori rẹ̀, nwọn a si kú nitorina, bi nwọn ba bà a jẹ́: Emi li OLUWA ti o yà wọn simimọ́.

10. Alejò kan kò gbọdọ jẹ ninu ohun mimọ́: alabagbé alufa, tabi alagbaṣe kò gbọdọ jẹ ninu ohun mimọ́ na.

11. Ṣugbọn bi alufa ba fi owo rẹ̀ rà ẹnikan, ki o jẹ ninu rẹ̀; ẹniti a si bi ninu ile rẹ̀, ki nwọn ki o ma jẹ ninu onjẹ rẹ̀.

12. Bi ọmọbinrin alufa na ba si ní alejò kan li ọkọ, obinrin na kò le jẹ ninu ẹbọ fifì ohun mimọ́.

Ka pipe ipin Lef 22