Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lef 2:9-16 Yorùbá Bibeli (YCE)

9. Alufa yio si mú ẹbọ-iranti ninu ohunjijẹ na, yio si sun u lori pẹpẹ: ẹbọ ti a fi iná ṣe, õrùn didùn si OLUWA.

10. Eyiti o si kù ninu ẹbọ ohunjijẹ, ki o jẹ́ ti Aaroni, ati ti awọn ọmọ rẹ̀: ohun mimọ́ julọ ni, ọrẹ-ẹbọ OLUWA ti a fi iná ṣe.

11. A kò gbọdọ fi iwukàra ṣe gbogbo ẹbọ ohunjijẹ ti ẹnyin o mú tọ̀ OLUWA wá: nitori ẹnyin kò gbọdọ sun iwukàra, tabi: oyinkoyin, ninu ọrẹ-ẹbọ OLUWA, ti a fi iná ṣe.

12. Bi ọrẹ-ẹbọ akọ́so, ẹnyin le mú wọn wá fun OLUWA: ṣugbọn a ki yio sun wọn lori pẹpẹ fun õrùn didùn.

13. Ati gbogbo ọrẹ-ẹbọ ohunjijẹ rẹ ni ki iwọ ki o fi iyọ̀ dùn; bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ jẹ ki iyọ̀ majẹmu Ọlọrun rẹ ki o má sí ninu ẹbọ ohunjijẹ rẹ: gbogbo ọrẹ-ẹbọ rẹ ni ki iwọ ki o fi iyọ̀ si.

14. Bi iwọ ba si mú ẹbọ ohunjijẹ akọ́so rẹ wá fun OLUWA, ki iwọ ki o si mú ṣiri ọkà daradara ti a yan lori iná wá fun ẹbọ ohunjijẹ akọ́so rẹ, ọkà gigún, ti ṣiri tutù.

15. Ki iwọ ki o si fi oróro sori rẹ̀, ki o si fi turari sori rẹ̀: ẹbọ ohunjijẹ ni.

16. Ki alufa ki o si sun ẹbọ-iranti rẹ̀, apakan ninu ọkà gigún rẹ̀, ati apakan ninu oróro rẹ̀, pẹlu gbogbo turari rẹ̀: ẹbọ ti a fi iná ṣe ni si OLUWA.

Ka pipe ipin Lef 2