Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lef 14:1-15 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. OLUWA si sọ fun Mose pe,

2. Eyi ni yio ma ṣe ofin adẹ́tẹ li ọjọ́ ìwẹnumọ́ rẹ̀: ki a mú u tọ̀ alufa wá:

3. Ki alufa ki o si jade sẹhin ibudó; ki alufa ki o si wò o, si kiyesi i, bi àrun ẹ̀tẹ na ba jiná li ara adẹ́tẹ na:

4. Nigbana ni ki alufa ki o paṣẹ pe, ki a mú ãye ẹiyẹ meji mimọ́ wá, fun ẹniti a o wẹ̀numọ́, pẹlu igi opepe, ati ododó, ati ewe-hissopu:

5. Ki alufa ki o paṣẹ pe ki a pa ọkan ninu ẹiyẹ nì ninu ohunèlo àmọ li oju omi ti nṣàn:

6. Niti ẹiyẹ alãye, ki o mú u, ati igi opepe, ati ododó, ati ewe-hissopu, ki o si fi wọn ati ẹiyẹ alãye nì bọ̀ inu ẹ̀jẹ ẹiyẹ ti a pa li oju omi ti nṣàn:

7. Ki o si fi wọ́n ẹniti a o wẹ̀numọ́ kuro ninu ẹ̀tẹ nigba meje, ki o si pè e ni mimọ́, ki o si jọwọ ẹiyẹ alãye nì lọwọ lọ si gbangba oko.

8. Ki ẹniti a o wẹ̀numọ́ nì ki o si fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o si fá gbogbo irun ori rẹ̀ kuro, ki o si wẹ̀ ara rẹ̀ ninu omi, ki o le mọ́: lẹhin eyinì ni ki o wọ̀ ibudó, ṣugbọn ki o gbé ẹhin ode agọ́ rẹ̀ ni ijọ́ meje.

9. Yio si ṣe ni ijọ́ keje, ni ki o fá gbogbo irun ori rẹ̀ kuro li ori rẹ̀, ati irungbọn rẹ̀, ati ipenpeju rẹ̀, ani gbogbo irun rẹ̀ ni ki o fá kuro: ki o si fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o si wẹ̀ ara rẹ̀ pẹlu ninu omi, on o si di mimọ́.

10. Ni ijọ́ kẹjọ ki o mú ọdọ-agutan meji akọ alailabùku wá, ati ọdọ-agutan kan abo ọlọdún kan alailabùku, ati idamẹwa mẹta òṣuwọn deali iyẹfun didara fun ẹbọ ohunjijẹ, ti a fi oróro pò, ati òṣuwọn logu oróro kan.

11. Ki alufa ti o sọ ọ di mimọ́ ki o mú ọkunrin na ti a o sọ di mimọ́, ati nkan wọnni wá, siwaju OLUWA, si ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ:

12. Ki alufa ki o mú akọ ọdọ-agutan kan, ki o si fi i ru ẹbọ ẹbi, ati òṣuwọn logu oróro, ki o si fì wọn li ẹbọ fifì niwaju OLUWA:

13. Ki o si pa akọ ọdọ-agutan na ni ibiti on o gbé pa ẹbọ ẹ̀ṣẹ ati ẹbọ sisun, ní ibi mimọ́ nì: nitoripe bi ẹbọ ẹ̀ṣẹ ti jẹ́ ti alufa, bẹ̃ si ni ẹbọ irekọja: mimọ́ julọ ni:

14. Ki alufa ki o si mú ninu ẹ̀jẹ ẹbọ ẹbi na, ki alufa ki o si fi i si eti ọtún ẹniti a o wẹ̀numọ́, ati si àtampako ọwọ́ ọtún rẹ̀, ati si àtampako ẹsẹ̀ ọtún rẹ̀:

15. Ki alufa ki o si mú ninu oróro òṣuwọn logu na, ki o si dà a si atẹlẹwọ òsi ara rẹ̀:

Ka pipe ipin Lef 14