Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Joel 2:20-32 Yorùbá Bibeli (YCE)

20. Ṣugbọn emi o ṣi ogun ariwa nì jinà rére kuro lọdọ nyin, emi o si le e lọ si ilẹ ti o ṣá, ti o si di ahoro, pẹlu oju rẹ̀ si okun ila-õrun, ati ẹhìn rẹ̀ si ipẹkùn okun, õrùn rẹ̀ yio si goke, õrùn buburu rẹ̀ yio si goke, nitoriti o ti ṣe ohun nla.

21. Má bẹ̀ru, iwọ ilẹ; jẹ ki inu rẹ dùn, ki o si yọ̀: nitori Oluwa yio ṣe ohun nla.

22. Ẹ má bẹ̀ru, ẹranko igbẹ: nitori pápa-oko aginju nrú, nitori igi nso eso rẹ̀, igi ọ̀pọtọ ati àjara nso eso ipá wọn.

23. Njẹ jẹ ki inu nyin dùn, ẹnyin ọmọ Sioni, ẹ si yọ̀ ninu Oluwa Ọlọrun nyin; nitoriti o ti fi akọrọ̀ ojò fun nyin bi o ti tọ́, on o si mu ki ojò rọ̀ silẹ fun nyin, akọrọ̀ ati arọ̀kuro ojò ni oṣù ikini.

24. Ati awọn ilẹ ipakà yio kún fun ọkà, ati ọpọ́n wọnni yio ṣàn jade pẹlu ọti-waini ati ororo.

25. Emi o si mu ọdun wọnni padà fun nyin wá, eyi ti ẽṣú on iru kòkoro jewejewe, ati iru kòkoro keji, ati iru kòkoro jewejewe miràn ti fi jẹ, awọn ogun nla mi ti mo rán sãrin nyin.

26. Ẹnyin o si jẹun li ọ̀pọlọpọ, ẹ o si yó, ẹ o si yìn orukọ Oluwa Ọlọrun nyin, ẹniti o fi iyanu ba nyin lò; oju kì o si tì awọn enia mi lai.

27. Ẹnyin o si mọ̀ pe, emi wà lãrin Israeli, ati pe: Emi li Oluwa Ọlọrun nyin, kì iṣe ẹlomiràn: oju kì yio si tì awọn enia mi lai.

28. Yio si ṣe, nikẹhìn emi o tú ẹmi mi jade si ara enia gbogbo; ati awọn ọmọ nyin ọkunrin, ati awọn ọmọ nyin obinrin yio ma ṣotẹlẹ, awọn arugbo nyin yio ma lá alá, awọn ọdọmọkunrin nyin yio ma riran:

29. Ati pẹlu si ara awọn ọmọ-ọdọ ọkunrin, ati si ara awọn ọmọ-ọdọ obinrin, li emi o tú ẹmi mi jade li ọjọ wọnni.

30. Emi o si fi iṣẹ iyanu hàn li ọrun ati li aiye, ẹjẹ̀ ati iná, ati ọwọ̀n ẹ̃fin.

31. A ó sọ õrùn di òkunkun, ati oṣùpá di ẹjẹ̀, ki ọjọ nla ati ẹ̀ru Oluwa to de.

32. Yio si ṣe ẹnikẹni ti o ba ke pè orukọ Oluwa li a o gbàla: nitori li oke Sioni ati ni Jerusalemu ni igbàla yio gbe wà, bi Oluwa ti wi, ati ninu awọn iyokù ti Oluwa yio pè.

Ka pipe ipin Joel 2