Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Joel 2:18-27 Yorùbá Bibeli (YCE)

18. Nigbana ni Oluwa yio jowú fun ilẹ rẹ̀, yio si kãnu fun enia rẹ̀.

19. Nitõtọ, Oluwa yio dahùn, yio si wi fun awọn enia rẹ̀ pe, Wò o emi o rán ọkà, ati ọti-waini, ati ororo si nyin, a o si fi wọn tẹ́ nyin lọrùn: emi kì yio si fi nyin ṣe ẹ̀gan mọ lãrin awọn keferi.

20. Ṣugbọn emi o ṣi ogun ariwa nì jinà rére kuro lọdọ nyin, emi o si le e lọ si ilẹ ti o ṣá, ti o si di ahoro, pẹlu oju rẹ̀ si okun ila-õrun, ati ẹhìn rẹ̀ si ipẹkùn okun, õrùn rẹ̀ yio si goke, õrùn buburu rẹ̀ yio si goke, nitoriti o ti ṣe ohun nla.

21. Má bẹ̀ru, iwọ ilẹ; jẹ ki inu rẹ dùn, ki o si yọ̀: nitori Oluwa yio ṣe ohun nla.

22. Ẹ má bẹ̀ru, ẹranko igbẹ: nitori pápa-oko aginju nrú, nitori igi nso eso rẹ̀, igi ọ̀pọtọ ati àjara nso eso ipá wọn.

23. Njẹ jẹ ki inu nyin dùn, ẹnyin ọmọ Sioni, ẹ si yọ̀ ninu Oluwa Ọlọrun nyin; nitoriti o ti fi akọrọ̀ ojò fun nyin bi o ti tọ́, on o si mu ki ojò rọ̀ silẹ fun nyin, akọrọ̀ ati arọ̀kuro ojò ni oṣù ikini.

24. Ati awọn ilẹ ipakà yio kún fun ọkà, ati ọpọ́n wọnni yio ṣàn jade pẹlu ọti-waini ati ororo.

25. Emi o si mu ọdun wọnni padà fun nyin wá, eyi ti ẽṣú on iru kòkoro jewejewe, ati iru kòkoro keji, ati iru kòkoro jewejewe miràn ti fi jẹ, awọn ogun nla mi ti mo rán sãrin nyin.

26. Ẹnyin o si jẹun li ọ̀pọlọpọ, ẹ o si yó, ẹ o si yìn orukọ Oluwa Ọlọrun nyin, ẹniti o fi iyanu ba nyin lò; oju kì o si tì awọn enia mi lai.

27. Ẹnyin o si mọ̀ pe, emi wà lãrin Israeli, ati pe: Emi li Oluwa Ọlọrun nyin, kì iṣe ẹlomiràn: oju kì yio si tì awọn enia mi lai.

Ka pipe ipin Joel 2