Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Joṣ 8:24-35 Yorùbá Bibeli (YCE)

24. O si ṣe, nigbati Israeli pari pipa gbogbo awọn ara ilu Ai ni igbẹ́, ati ni aginjù ni ibi ti nwọn lé wọn si, ti gbogbo wọn si ti oju idà ṣubu, titi a fi run wọn, ni gbogbo awọn ọmọ Israeli pada si Ai, nwọn si fi oju idà kọlù u.

25. O si ṣe, gbogbo awọn ti o ṣubu ni ijọ́ na, ati ọkunrin ati obinrin, jẹ́ ẹgba mẹfa, ani gbogbo ọkunrin Ai.

26. Nitoriti Joṣua kò fà ọwọ́ rẹ̀ ti o fi nà ọ̀kọ sẹhin, titi o fi run gbogbo awọn ara ilu Ai tútu.

27. Kìki ohun-ọ̀sin ati ikogun ilu na ni Israeli kó fun ara wọn, gẹgẹ bi ọ̀rọ OLUWA ti o palaṣẹ fun Joṣua.

28. Joṣua si kun Ai, o sọ ọ di òkiti lailai, ani ahoro titi di oni-oloni.

29. Ọba Ai li o si so rọ̀ lori igi titi di aṣalẹ: bi õrùn si ti wọ̀, Joṣua paṣẹ ki a sọ okú rẹ̀ kuro lori igi kalẹ, ki a si wọ́ ọ jù si atiwọ̀ ibode ilu na, ki a si kó òkiti nla okuta lé e lori, ti mbẹ nibẹ̀ titi di oni-oloni.

30. Nigbana ni Joṣua tẹ́ pẹpẹ kan fun OLUWA, Ọlọrun Israeli, li òke Ebali,

31. Gẹgẹ bi Mose iranṣẹ OLUWA ti paṣẹ fun awọn ọmọ Israeli, gẹgẹ bi a ti kọ ọ ninu iwé ofin Mose, pẹpẹ odidi okuta, lara eyiti ẹnikan kò fi irin kan: nwọn si ru ẹbọ sisun lori rẹ̀ si OLUWA, nwọn si ru ẹbọ alafia.

32. O si kọ apẹrẹ ofin Mose sara okuta na, ti o kọ niwaju awọn ọmọ Israeli.

33. Ati gbogbo Israeli, ati awọn àgba wọn, ati awọn olori, ati awọn onidajọ wọn, duro li apa ihin ati li apa ọhún apoti ẹrí niwaju awọn alufa awọn ọmọ Lefi, ti o rù apoti majẹmu OLUWA, ati alejò ati ibilẹ; àbọ wọn kọjusi òke Gerisimu; ati àbọ wọn kọjusi òke Ebali, gẹgẹ bi Mose iranṣẹ OLUWA ti paṣẹ rí, pe ki nwọn ki o sure fun awọn enia Israeli.

34. Lẹhin eyi o si kà gbogbo ọ̀rọ ofin, ibukún ati egún, gẹgẹ bi gbogbo eyiti a kọ ninu iwé ofin.

35. Kò kù ọ̀rọ kan ninu gbogbo eyiti Mose palaṣẹ, ti Joṣua kò kà niwaju gbogbo ijọ Israeli, ati awọn obinrin, ati awọn ọmọ wẹrẹ, ati awọn alejò ti nrìn lãrin wọn.

Ka pipe ipin Joṣ 8