Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Joṣ 8:21-31 Yorùbá Bibeli (YCE)

21. Nigbati Joṣua ati gbogbo Israeli ri bi awọn ti o ba ti gbà ilu, ti ẹ̃fi ilu na si gòke, nwọn si yipada, nwọn si pa awọn ọkunrin Ai.

22. Awọn ti ara keji si yọ si wọn lati ilu na wá; bẹ̃ni nwọn wà li agbedemeji Israeli, awọn miran li apa ihin, awọn miran li apa ọhún: nwọn si pa wọn, bẹ̃ni nwọn kò si jẹ ki ọkan ki o kù tabi ki o sálọ ninu wọn.

23. Nwọn si mú ọba Ai lãye, nwọn si mú u wá sọdọ Joṣua.

24. O si ṣe, nigbati Israeli pari pipa gbogbo awọn ara ilu Ai ni igbẹ́, ati ni aginjù ni ibi ti nwọn lé wọn si, ti gbogbo wọn si ti oju idà ṣubu, titi a fi run wọn, ni gbogbo awọn ọmọ Israeli pada si Ai, nwọn si fi oju idà kọlù u.

25. O si ṣe, gbogbo awọn ti o ṣubu ni ijọ́ na, ati ọkunrin ati obinrin, jẹ́ ẹgba mẹfa, ani gbogbo ọkunrin Ai.

26. Nitoriti Joṣua kò fà ọwọ́ rẹ̀ ti o fi nà ọ̀kọ sẹhin, titi o fi run gbogbo awọn ara ilu Ai tútu.

27. Kìki ohun-ọ̀sin ati ikogun ilu na ni Israeli kó fun ara wọn, gẹgẹ bi ọ̀rọ OLUWA ti o palaṣẹ fun Joṣua.

28. Joṣua si kun Ai, o sọ ọ di òkiti lailai, ani ahoro titi di oni-oloni.

29. Ọba Ai li o si so rọ̀ lori igi titi di aṣalẹ: bi õrùn si ti wọ̀, Joṣua paṣẹ ki a sọ okú rẹ̀ kuro lori igi kalẹ, ki a si wọ́ ọ jù si atiwọ̀ ibode ilu na, ki a si kó òkiti nla okuta lé e lori, ti mbẹ nibẹ̀ titi di oni-oloni.

30. Nigbana ni Joṣua tẹ́ pẹpẹ kan fun OLUWA, Ọlọrun Israeli, li òke Ebali,

31. Gẹgẹ bi Mose iranṣẹ OLUWA ti paṣẹ fun awọn ọmọ Israeli, gẹgẹ bi a ti kọ ọ ninu iwé ofin Mose, pẹpẹ odidi okuta, lara eyiti ẹnikan kò fi irin kan: nwọn si ru ẹbọ sisun lori rẹ̀ si OLUWA, nwọn si ru ẹbọ alafia.

Ka pipe ipin Joṣ 8