Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Joṣ 4:13-24 Yorùbá Bibeli (YCE)

13. Ìwọn ọkẹ meji enia ti o mura ogun, rekọja niwaju OLUWA fun ogun, si pẹtẹlẹ̀ Jeriko.

14. Li ọjọ́ na OLUWA gbé Joṣua ga li oju gbogbo Israeli: nwọn si bẹ̀ru rẹ̀, gẹgẹ bi nwọn ti bẹ̀ru Mose li ọjọ́ aiye rẹ̀ gbogbo.

15. OLUWA si wi fun Joṣua pe,

16. Paṣẹ fun awọn alufa ti o rù apoti ẹri nì pe, ki nwọn ki o ti inu Jordani jade.

17. Nitorina Joṣua paṣẹ fun awọn alufa wipe, Ẹ ti inu Jordani jade.

18. O si ṣe, nigbati awọn alufa ti o rù apoti majẹmu OLUWA ti ãrin Jordani jade, ti awọn alufa si gbé atẹlẹsẹ̀ wọn soke si ilẹ gbigbẹ, ni omi Jordani pada si ipò rẹ̀, o si ṣàn bò gbogbo bèbe rẹ̀, gẹgẹ bi ti iṣaju.

19. Awọn enia si ti inu Jordani gòke ni ijọ́ kẹwa oṣù kini, nwọn si dó ni Gilgali, ni ìha ìla-õrùn Jeriko.

20. Ati okuta mejila wọnni ti nwọn gbé ti inu Jordani lọ, ni Joṣua tòjọ ni Gilgali.

21. O si wi fun awọn ọmọ Israeli pe, Nigbati awọn ọmọ nyin yio bère lọwọ awọn baba wọn lẹhin ọ̀la wipe, Ẽredi okuta wọnyi?

22. Nigbana li ẹnyin o jẹ ki awọn ọmọ nyin ki o mọ̀ pe, Israeli là Jordani yi kọja ni ilẹ gbigbẹ.

23. Nitoriti OLUWA Ọlọrun nyin mu omi Jordani gbẹ kuro niwaju nyin, titi ẹnyin fi là a kọja, gẹgẹ bi OLUWA Ọlọrun nyin ti ṣe si Okun Pupa, ti o mu gbẹ kuro niwaju wa, titi awa fi là a kọja:

24. Ki gbogbo enia aiye ki o le mọ ọwọ́ OLUWA, pe o lagbara; ki nwọn ki o le ma bẹ̀ru OLUWA Ọlọrun nyin lailai.

Ka pipe ipin Joṣ 4