Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Joṣ 22:18-28 Yorùbá Bibeli (YCE)

18. Ti ẹnyin fi pada kuro lẹhin OLUWA li oni? Yio si ṣe, bi ẹnyin ti ṣọ̀tẹ si OLUWA li oni, li ọla, on o binu si gbogbo ijọ Israeli.

19. Njẹ bi o ba ṣepe ilẹ iní nyin kò ba mọ́, ẹ rekọja si ilẹ iní OLUWA, nibiti agọ́ OLUWA ngbé, ki ẹ si gbà ilẹ-iní lãrin wa: ṣugbọn ẹnyin má ṣe ṣọ̀tẹ si OLUWA, bẹ̃ni ki ẹ má ṣe ṣọ̀tẹ si wa, ni mimọ pẹpẹ miran fun ara nyin lẹhin pẹpẹ OLUWA Ọlọrun wa.

20. Ṣe bẹ̃ni Akani ọmọ Sera da ẹ̀ṣẹ niti ohun ìyasọtọ, ti ibinu si dé sori gbogbo ijọ Israeli? ọkunrin na kò nikan ṣegbé ninu ẹ̀ṣẹ rẹ̀.

21. Nigbana ni awọn ọmọ Reubeni, ati awọn ọmọ Gadi, ati àbọ ẹ̀ya Manasse dahùn, nwọn si wi fun awọn olori ẹgbẹgbẹrun Israeli pe,

22. OLUWA, Ọlọrun awọn ọlọrun, OLUWA Ọlọrun awọn ọlọrun, On mọ̀, Israeli pẹlu yio si mọ̀; bi o ba ṣepe ni ìṣọtẹ ni, tabi bi ni irekọja si OLUWA, (má ṣe gbà wa li oni,)

23. Ni awa fi mọ pẹpẹ fun ara wa, lati yipada kuro lẹhin OLUWA; tabi bi o ba ṣe pe lati ru ẹbọ sisun, tabi ẹbọ ohunjijẹ, tabi ẹbọ alafia lori rẹ̀, ki OLUWA tikala rẹ̀ ki o bère rẹ̀.

24. Bi o ba ṣepe awa kò kuku ṣe e nitori aniyàn, ati nitori nkan yi pe, Lẹhinọla awọn ọmọ nyin le wi fun awọn ọmọ wa pe, Kili o kàn nyin niti OLUWA, Ọlọrun Israeli?

25. Nitoriti Ọlọrun ti fi Jordani pàla li agbedemeji awa ati ẹnyin, ẹnyin ọmọ Reubeni, ati awọn ọmọ Gadi; ẹnyin kò ní ipín niti OLUWA: bẹ̃li awọn ọmọ nyin yio mu ki awọn ọmọ wa ki o dẹkun ati ma bẹ̀ru OLUWA.

26. Nitorina li a ṣe wipe, Ẹ jẹ ki a mura nisisiyi lati mọ pẹpẹ kan, ki iṣe fun ẹbọ sisun, tabi fun ẹbọ kan:

27. Ṣugbọn ẹrí ni li agbedemeji awa ati ẹnyin, ati awọn iran wa lẹhin wa, ki awa ki o le ma fi ẹbọ sisun wa, ati ẹbọ wa, pẹlu ẹbọ alafia wa jọsìn fun OLUWA niwaju rẹ̀; ki awọn ọmọ nyin ki o má ba wi fun awọn ọmọ wa lẹhinọla pe, Ẹnyin kò ní ipín niti OLUWA.

28. Nitorina ni awa ṣe wipe, Yio si ṣe, nigbati nwọn ba wi bẹ̃ fun wa, tabi fun awọn iran wa lẹhinọla, awa o si wipe, Ẹ wò apẹrẹ pẹpẹ OLUWA, ti awọn baba wa mọ, ki iṣe fun ẹbọ sisun, bẹ̃ni ki iṣe fun ẹbọ; ṣugbọn o jasi ẹrí li agbedemeji awa ati ẹnyin.

Ka pipe ipin Joṣ 22