Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Joṣ 2:17-22 Yorùbá Bibeli (YCE)

17. Awọn ọkunrin na wi fun u pe, Ara wa o dá niti ibura rẹ yi, ti iwọ mu wa bú.

18. Kiyesi i, nigbati awa ba dé inu ilẹ na, iwọ o so okùn owú ododó yi si oju-ferese ti iwọ fi sọ̀ wa kalẹ: iwọ o si mú baba rẹ, ati iya rẹ, ati awọn arakunrin rẹ, ati gbogbo ara ile baba rẹ, wá ile sọdọ rẹ.

19. Yio si ṣe, ẹnikẹni ti o ba jade lati inu ilẹkun ile rẹ lọ si ode, ẹ̀jẹ rẹ̀ yio wà li ori ara rẹ̀, awa o si wà li aijẹbi: ati ẹnikẹni ti o ba wà pẹlu rẹ ni ile, ẹ̀jẹ rẹ̀ yio wà li ori wa, bi ẹnikẹni ba fọwọkàn a.

20. Bi o ba si sọ ọ̀ran wa yi, nigbana ni ara wa o dá niti ibura rẹ ti iwọ mu wa bú yi.

21. O si wipe, Gẹgẹ bi ọ̀rọ nyin, bẹ̃ni ki o ri. O si rán wọn lọ, nwọn si lọ: o si so okùn ododó na si oju-ferese.

22. Nwọn si lọ, nwọn si dé ori òke, nwọn si gbé ibẹ̀ ni ijọ́ mẹta, titi awọn alepa fi pada: awọn alepa wá wọn ni gbogbo ọ̀na, ṣugbọn nwọn kò ri wọn.

Ka pipe ipin Joṣ 2