Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Joṣ 10:25-32 Yorùbá Bibeli (YCE)

25. Joṣua si wi fun wọn pe, Ẹ má ṣe bẹ̀ru, ẹ má si ṣe fòya; ẹ ṣe giri, ki ẹ si mu àiya le: nitoripe bayi li OLUWA yio ṣe si awọn ọtá nyin gbogbo ti ẹnyin mbájà.

26. Lẹhin na ni Joṣua si kọlù wọn, o si pa wọn, o si so wọn rọ̀ lori igi marun: nwọn si sorọ̀ lori igi titi di aṣalẹ.

27. O si ṣe li akokò ìwọ-õrùn, Joṣua paṣẹ, nwọn si sọ̀ wọn kalẹ kuro lori igi, nwọn si gbé wọn sọ sinu ihò na ninu eyiti nwọn ti sapamọ́ si, nwọn si fi okuta nla di ẹnu ihò na, ti o wà titi di oni-oloni.

28. Li ọjọ́ na ni Joṣua kó Makkeda, o si fi oju idà kọlù u, ati ọba rẹ̀; o pa wọn run patapata, ati gbogbo ọkàn ti mbẹ ninu rẹ̀, kò kù ẹnikan silẹ: o si ṣe si ọba Makkeda gẹgẹ bi o ti ṣe si ọba Jeriko.

29. Joṣua si kọja lati Makkeda lọ si Libna, ati gbogbo Israeli pẹlu rẹ̀, o si fi ijà fun Libna:

30. OLUWA si fi i lé Israeli lọwọ pẹlu, ati ọba rẹ̀: o si fi oju idà kọlù u, ati gbogbo ọkàn ti o wà ninu rẹ̀; kò kù ẹnikan ninu rẹ̀; o si ṣe si ọba rẹ̀ gẹgẹ bi o ti ṣe si ọba Jeriko.

31. Joṣua si kọja lati Libna lọ si Lakiṣi, ati gbogbo Israeli pẹlu rẹ̀, o si dótì i, o si fi ìja fun u.

32. OLUWA si fi Lakiṣi lé Israeli lọwọ, o si kó o ni ijọ́ keji, o si fi oju idà kọlù u, ati gbogbo ọkàn ti o wà ninu rẹ̀, gẹgẹ bi gbogbo eyiti o ṣe si Libna.

Ka pipe ipin Joṣ 10