Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Joṣ 10:17-26 Yorùbá Bibeli (YCE)

17. A si sọ fun Joṣua pe, A ri awọn ọba marun ni ifarapamọ́ ni ihò ni Makkeda.

18. Joṣua si wipe, Ẹ yí okuta nla di ẹnu ihò na, ki ẹ si yàn enia sibẹ̀ lati ṣọ́ wọn:

19. Ṣugbọn ẹnyin, ẹ má ṣe duro, ẹ lepa awọn ọtá nyin, ki ẹ si kọlù wọn lẹhin; ẹ máṣe jẹ ki nwọn ki o wọ̀ ilu wọn lọ: nitoriti OLUWA Ọlọrun nyin ti fi wọn lé nyin lọwọ.

20. O si ṣe, nigbati Joṣua ati awọn ọmọ Israeli pa wọn ni ipakupa tán, titi a fi run wọn, ti awọn ti o kù ninu wọn wọ̀ inu ilu olodi lọ,

21. Gbogbo enia si pada si ibudó sọdọ Joṣua ni Makkeda li alafia: kò sí ẹni kan ti o yọ ahọn rẹ̀ si awọn ọmọ Israeli.

22. Nigbana ni Joṣua wipe, Ẹ ṣi ẹnu ihò na, ki ẹ si mú awọn ọba mararun na jade kuro ninu ihò tọ̀ mi wá.

23. Nwọn si ṣe bẹ̃, nwọn si mú awọn ọba mararun nì jade lati inu ihò na tọ̀ ọ wá, ọba Jerusalemu, ọba Hebroni, ọba Jarmutu, ọba Lakiṣi, ati ọba Egloni.

24. O si ṣe, nigbati nwọn mú awọn ọba na tọ̀ Joṣua wá, ni Joṣua pè gbogbo awọn ọkunrin Israeli, o si wi fun awọn olori awọn ọmọ-ogun ti o bá a lọ pe, Ẹ sunmọ ihin, ẹ si fi ẹsẹ̀ nyin lé ọrùn awọn ọba wọnyi. Nwọn si sunmọ wọn, nwọn si gbé ẹsẹ̀ wọn lé wọn li ọrùn.

25. Joṣua si wi fun wọn pe, Ẹ má ṣe bẹ̀ru, ẹ má si ṣe fòya; ẹ ṣe giri, ki ẹ si mu àiya le: nitoripe bayi li OLUWA yio ṣe si awọn ọtá nyin gbogbo ti ẹnyin mbájà.

26. Lẹhin na ni Joṣua si kọlù wọn, o si pa wọn, o si so wọn rọ̀ lori igi marun: nwọn si sorọ̀ lori igi titi di aṣalẹ.

Ka pipe ipin Joṣ 10