Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Joṣ 10:1-6 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. O SI ṣe, nigbati Adoni-sedeki ọba Jerusalemu gbọ́ pe Joṣua ti kó Ai, ti o si pa a run patapata; bi o ti ṣe si Jeriko ati si ọba rẹ̀, bẹ̃li o si ṣe si Ai ati si ọba rẹ̀; ati bi awọn ara Gibeoni ti bá Israeli ṣọrẹ, ti nwọn si ngbé ãrin wọn;

2. Nwọn bẹ̀ru pipọ̀, nitoriti Gibeoni ṣe ilu nla, bi ọkan ninu awọn ilu ọba, ati nitoriti o tobi jù Ai lọ, ati gbogbo ọkunrin inu rẹ̀ jẹ́ alagbara.

3. Nitorina Adoni-sedeki ọba Jerusalemu ranṣẹ si Hohamu ọba Hebroni, ati si Piramu ọba Jarmutu, ati si Jafia ọba Lakiṣi, ati si Debiri ọba Egloni, wipe,

4. Ẹ gòke tọ̀ mi wá, ki ẹ si ràn mi lọwọ, ki awa ki o le kọlù Gibeoni: nitoriti o bá Joṣua ati awọn ọmọ Israeli ṣọrẹ.

5. Awọn ọba Amori mararun, ọba Jerusalemu, ọba Hebroni, ọba Jarmutu, ọba Lakiṣi, ati ọba Egloni, kó ara wọn jọ, nwọn si gòke, awọn ati gbogbo ogun wọn, nwọn si dótì Gibeoni, nwọn si fi ìja fun u.

6. Awọn ọkunrin Gibeoni si ranṣẹ si Joṣua ni ibudó ni Gilgali, wipe, Má ṣe fà ọwọ́ rẹ sẹhin kuro lọdọ awọn iranṣẹ rẹ; gòke tọ̀ wa wá kánkán, ki o si gbà wa, ki o si ràn wa lọwọ: nitoriti gbogbo awọn ọba Amori ti ngbé ori òke kójọ pọ̀ si wa.

Ka pipe ipin Joṣ 10