Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jer 9:2-17 Yorùbá Bibeli (YCE)

2. A! emi iba ni buka ero ni iju, ki emi ki o le fi enia mi silẹ, ki nlọ kuro lọdọ wọn! nitori gbogbo nwọn ni panṣaga, ajọ alarekereke enia ni nwọn.

3. Nwọn si fà ahọn wọn bi ọrun fun eke; ṣugbọn nwọn kò ṣe akoso fun otitọ lori ilẹ, nitoripe nwọn ti inu buburu lọ si buburu nwọn kò si mọ̀ mi, li Oluwa wi.

4. Ẹ mã ṣọra, olukuluku nyin lọdọ aladugbo rẹ̀, ki ẹ má si gbẹkẹle arakunrin karakunrin: nitoripe olukuluku arakunrin fi arekereke ṣẹtan patapata, ati olukuluku aladugbo nsọ̀rọ ẹnilẹhin.

5. Ẹnikini ntàn ẹnikeji rẹ̀ jẹ, nwọn kò si sọ otitọ: nwọn ti kọ́ ahọn wọn lati ṣeke, nwọn si ti ṣe ara wọn lãrẹ lati ṣe aiṣedede.

6. Ibugbe rẹ mbẹ lãrin ẹ̀tan; nipa ẹ̀tan nwọn kọ̀ lati mọ̀ mi, li Oluwa wi.

7. Nitorina bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, sa wò o, emi o yọ́ wọn, emi o si dán wọn wò, nitori kili emi o ṣe fun ọmọbinrin enia mi.

8. Ahọn wọn dabi ọfa ti a ta, o nsọ ẹ̀tan, ẹnikini nfi ẹnu rẹ̀ sọ alafia fun ẹnikeji rẹ̀, ṣugbọn li ọkàn rẹ̀ o ba dè e.

9. Emi kì yio ha bẹ̀ wọn wò nitori nkan wọnyi? li Oluwa wi, ọkàn mi kì yio ha gbẹsan lara orilẹ-ède bi iru eyi?

10. Fun awọn oke-nla ni emi o gbe ẹkún ati ohùnrere soke, ati ẹkún irora lori papa oko aginju wọnnì, nitoriti nwọn jona, ẹnikan kò le kọja nibẹ, bẹ̃ni a kò gbọ́ ohùn ẹran-ọsin, lati ẹiyẹ oju-ọrun titi de ẹranko ti sa kuro, nwọn ti lọ.

11. Emi o sọ Jerusalemu di okiti àlapa, ati iho awọn ikõko, emi o si sọ ilu Juda di ahoro, laini olugbe.

12. Tani enia na ti o gbọ́n, ti o moye yi? ati tani ẹniti ẹnu Oluwa ti sọ fun, ki o ba le kede rẹ̀, pe: kili o ṣe ti ilẹ fi ṣegbe, ti o si sun jona bi aginju, ti ẹnikan kò kọja nibẹ?

13. Oluwa si wipe, nitoriti nwọn ti kọ̀ ofin mi silẹ ti mo ti gbe kalẹ niwaju wọn, ti nwọn kò si gbà ohùn mi gbọ́, bẹ̃ni nwọn kò si rin ninu rẹ̀.

14. Ṣugbọn nwọn ti rin nipa agidi ọkàn wọn ati nipasẹ Baalimu, ti awọn baba wọn kọ́ wọn:

15. Nitorina bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli wi; sa wò o, awọn enia yi pãpa ni emi o fi wahala bọ́, emi o si mu wọn mu omi orõro.

16. Emi o si tú wọn ka ninu awọn keferi, ti awọn tikarawọn ati baba wọn kò mọ ri, emi o si rán idà si wọn titi emi o fi run wọn.

17. Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, Ẹ kiye si i, ki ẹ si pe awọn obinrin ti nṣọfọ, ki nwọn wá; ẹ si ranṣẹ pè awọn obinrin ti o moye, ki nwọn wá.

Ka pipe ipin Jer 9